Aṣiri ohun ti Ọbasanjọ tori ẹ lọ silẹ Olominira Benin ree

Faith Adebọla

Lati ọsẹ to kọja ni ariwo ti gba ikanni ayelujara, tawọn iweeroyin paapaa si n gbe e pe Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti i ṣe aarẹ ilẹ wa tẹlẹ lọ si ilẹ Benin.

Ohun ti gbogbo aye n sọ ni pe niṣe ni baba yii lọọ ki olori orileede naa tẹlẹ, Nicephore Soglo, fun ti iyawo rẹ, Roseline, to ku lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keje, to kọja yii. Loootọ lo lọ sibẹ to lọọ ki ọkunrin yii, ṣugbọn o kan fi iyẹn boju ni gẹgẹ bi awọn ti wọn mọ nipa ohun to n ṣẹlẹ naa ṣe tu aṣiri ọrọ yii fun ALAROYE.

Wọn ni awọn agbaagba Yoruba kan ni wọn lọọ ba Ọbasanjọ, ti wọn si rọ ọ pe ko ma wo ọrọ to wa nilẹ yii niran rara, ko jọwọ, ko ba awọn lọọ ri aarẹ ilẹ Benin lati le yanju wahala to n lọ naa.

ALAROYE gbọ pe baba naa kọkọ yari pe oun ko ni i lọ, nitori Sunday Igboho ti bu oun naa ri. Ṣugbọn agba ki i wa lọja ki ori ọmọ tuntun wọ ni wọn fi ọrọ naa ṣe. Ti awọn agbaagba naa si sọ pe eyi to wa nilẹ yii ti kọja ọrọ Igboho nikan, nitori ẹtẹ awo ni ẹrin  ọgbẹri, ati pe ti oju ba ti ajijagbara naa, gbogbo Yoruba ni oju ti.

Eyi lo fa a ti Ọbasanjọ fi lọ si ilẹ Benin. Ẹni to sọrọ yii fun wa sọ pe Oloye Oluṣẹgun ti lọ si ilu naa o ti de ki awo ọrọ naa too lu sita rara fun ẹnikẹni, nitori ohun ti wọn fẹnuko si ni pe ijọba Buhari tabi ẹnikẹni ko gbọdọ mọ igba ti ọkunrin naa yoo lọ.

Ohun naa lo ṣe jẹ pe Ọbasanjọ ti lọ, o si ti pada si Naijiria ki ẹnikẹni too gbọ nipa irinajo ọhun.

Bakan naa la gbọ lati ẹnu awọn ti wọn mọ bọrọ naa ṣe n lọ pe ọkan lara ohun ti Ọbasanjọ beere lọwọ Aarẹ Patrice Talon, olori ilẹ Benin ni pe labẹ bo ṣe wu ko ri, wọn ko gbọdọ da Sunday Igboho pada si Naijiria, wọn ko si gbọdọ gba ijọba ilẹ wa laaye lati lo ọgbọn ẹwẹ kankan ki wọn fi da a pada.

Leave a Reply