Aṣiri tu, wọn ni wọn pa Dapọ ẹgbọn iyawo Bukọla Saraki ni o

Dada Ajikanje

Ni kete ti ọwọ ti tẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ Oloogbe Dapọ Ọjọra ti wọn sọ pe o yinbọn para ẹ, ni ẹru ti n ba awọn mi-in ti wọn sunmọ ọn, ki awọn ọlọpaa ma baa mu wọn wi pe wọn ni aroye i ṣe lagọ wọn.

Lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii ni iroyin iku ọkunrin naa gbode kan,  ohun ti awọn eeyan si n sọ kiri ni pe funra Dapọ lo yinbọn para ẹ.

ALAROYE gbọ pe ọrọ ti wọn n gbe kiri yii ba awọn eeyan ẹ ninu jẹ gidi, eyi to mu wọn ranṣẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa l’Ekoo lati tọpinpin ohun to ṣẹlẹ gan-an.

Ni kete tawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii wọn, ẹnikan to ti n ba a ṣiṣẹ lati nnkan bi ọdun mẹrindinlogun sẹyin ni wọn kọkọ mu, bẹẹ ẹni yii gan-an lo kọkọ ri oku arakunrin naa ninu agbara ẹjẹ ẹ, latigba naa lo si ti wa lọdọ awọn ọlọpaa nibi to ti n ṣalaye ohun to mọ gan an.

Yatọ si eyi, ohun ti a tun gbọ ni pe nibi ti wọn ti ba ọkunrin yii, ati bi ọta ibọn ṣe fọn kiri ilẹ tọka si i pe iku ẹ lọwọ kan abosi ninu pẹlu bi wọn ti ṣe kọkọ n gbe e kiri wi pe oun gan-an lo yinbọn fun ara ẹ lori.

Bi iwadii ọhun ṣe bẹrẹ niyẹn o, eyi gan-an ni wọn lo ko wahala ba awọn eeyan ti wọn sun mọ ọn, paapaa awọn ti wọn jọ n ṣe wọle-wọde, ti wọn fi n wo o wi pe wahala to de ba ẹni to ti fi ọdun mẹrindinlogun ṣiṣẹ pẹlu ẹ yii n bọ waa kan awọn naa laipẹ.

Ṣa o, bi awọn eeyan kan ṣe n sọ pe iku ẹ lọwọ ninu, bẹẹ lawọn mi-in ṣi n tẹnu mọ ọn pe okoowo ọkunrin naa ti ko lọ deede mọ, ati iporuru ọkan to ba a latigba tiyawo ẹ ti kọ ọ silẹ ṣee ṣe ko mu un gbẹmi ara ẹ gẹgẹ bi wọn ti ṣe n gbe ọrọ ọhun kiri tẹlẹ.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: