Aṣiri tu! Wọn ti darukọ awọn akẹkọọ to pa Sylvester, ati bi wọn ṣe pa a

Faith Adebọla, Eko

Ọkan ninu awọn ọmọleewe Dowen College, toun ati Oloogbe Sylvester Oromoni jọ n gbe yara kan naa, ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lọjọ tawọn ọmọde afurasi ẹlẹgbẹ okunkun lọọ da ẹmi rẹ legbodo ninu yara naa, ọmọ ọhun, ti ko fẹẹ sọ orukọ ara rẹ sọ pe niṣoju oun ati awọn yooku tawọn jọ wa ni yara ni wọn ṣe din dundu iya buruku fun Sylvester, o si darukọ awọn mẹrin toun mọ ti wọn wa lara awọn to huwa odoro nla ọhun.

Ninu alaye tọmọ naa ṣe, eyi ti mọlẹbi Sylvester kan, Timi Oromoni, fi sori atẹ ayelujara tuita rẹ, o ni irọlẹ, ni nnkan bii aago meje ọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun yii, lawọn siniọ bii mẹfa ja wọ ileegbee awọn akẹkọọ lojiji, ni ile tawọn n gbe ninu ọgba ileewe naa, bi wọn ṣe wọle ni wọn pa’na yara naa, Siniọ Favor lo pa’na.

“Wọn o ki i ṣe marun-un, ọmọkunrin mẹfa ni wọn, mo ri wọn daadaa, ṣugbọn mi o mọ awọn ti wọn lọwọ ninu lilu Slyvester lalubami, boya gbogbo wọn ni, tori wọn ti pana nigba yẹn, firi firi la kan n wo.

‘‘Awọn to da mi loju, ti wọn wa lọjọ yẹn ni Favor, Edwin, Anslem ati Micheal. O da bii pe Edwin lo ko wọn wa, oun lo n paṣẹ fawọn to ku.

‘‘Bi wọn ṣe bẹrẹ si i lu ẹni ti wọn wa wa ọhun, to si n bẹ wọn pe ki wọn ṣaanu oun, ojiji lọmọ naa ja bọ latori bẹẹdi to dubulẹ si tẹlẹ, tori gbogbo wa jọ n takurọsọ lọwọ ni wọn ja wọle. Nigba ti Sly (Sylvester lo pe bẹẹ) ṣubu, wọn tun bẹrẹ si i lu u.

‘‘Ẹyin naa ni wọn pe wa, Anslem sọrọ pe awọn ofin ileewe yii ti su oun, ti a ba si fi le lọọ ṣofofo awọn bi Sly ṣe ṣe, kekere lohun tawọn ṣe fun un yii maa jẹ lẹgbẹẹ iya tawọn maa fi jẹ onitọhun.

‘‘Ọmọ naa ṣi n jẹrora nilẹ to na gbalaja si nigba yẹn, ko le da dide, bi awọn siniọ yii si ṣe n jade lọkọọkan ni wọn n fẹsẹ gba Sly nipaa, omi-in fibinu tẹ ẹ lori mọlẹ.  

‘‘Nigba ti wọn lọ tan, a gbiyanju lati ṣaajo ẹ, a gbe e dide sori bẹẹdi ẹ pada. Ṣugbọn nitori ikilọ awọn siniọ yẹn, ko sẹni to laya lati lọọ fẹjọ sun ninu wa. Afi nigba tilẹ mọ, ti Sylvester ni gbogbo ara lo n ro oun, ko si le fẹsẹ ara ẹ rin mọ. Awọn siniọ yii tun pe wa sinu yara wọn, wọn ni a o gbọdọ sọ ohun to ṣẹlẹ fawọn ọga ileewe o, pe ti a ba sọ, awọn maa mọ, awọn si maa fiya jẹ wa. Wọn ni tẹnikẹni ba beere ohun to ṣe e lọwọ wa, ka sọ fun wọn pe o lọọ gba bọọlu ni, ibẹ lo ti ṣeṣe, a la a ti gbọ.

‘‘Ọga to n bojuto ile gbigbe ninu ọgba yẹn mọ ohun o ṣẹlẹ, o mọ pe wọn lu Sylvester ni, o si ya mi lẹnu ti wọn n wa n purọ lori ayelujara pe awọn o mọ, wọn mọ pe ki i ṣe bọọlu lo lọọ gba. Koda, laaarọ ọjọ keji ti wọn gbe Sly lọ sileewosan inu ọgba ileewe, o han pe wọn lu u ni, ko si bọọlu to le ṣẹ eeyan leegun bẹẹ yẹn, ati pe ko si eto bọọlu gbigba lọsẹ yẹn, ko tiẹ si eto ere idaraya kankan lori atẹ ikẹkọọ wa.

‘‘Mo gbiyanju lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun ọga agba ileewe wa (principal), ṣugbọn niṣe ni wọn jagbe mọ wa pe ka yee sọ kotokoto, wọn ni bọọlu lo gba. Ko si pẹ sigba naa ni mọlẹbi Sly waa gbe e lọ.”

Alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu kejila yii, iyẹn lọjọ kẹrin ti wọn ṣakọlu si i, ni ọmọdekunrin Sylvester Oromoni Juniọ, akẹkọọ ileewe Dowen College, to wa ni Lẹkki, nipinlẹ Eko, doloogbe lọsibitu kan nipinlẹ Delta, ti baba rẹ gbe e lọ fun itọju iwosan.’’

Leave a Reply