Aṣiri tu: Wọn ti mu ṣọja to n ta ibọn fawọn ọdaran

Adewale Adeoye

Obitibiti ọta ibọn ati ohun ija oloro mi-in ni wọn gba lọwọ ṣọja kan, Sajẹnti Saad Adamu, to jẹ pe ṣe lo maa n ko awọn ohun ija oloro lọ fawọn ọbayejẹ ẹda kan ti wọn n da alaafia ilu laamu nipinlẹ Borno. Inu paali ẹja lo maa n tọju awọn ọta ibọn naa si, ti yoo si dọgbọn gbe e lọ fun wọn. Ṣugbọn ni bayii, ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ẹ.

ALAROYE gbọ pe ikọ ologun ‘3 Division’,  to wa ni Jos, nipinlẹ Plateau, ni afurasi ọdaran ọhun n ba ṣiṣẹ ṣugbọn ilu Maiduguri, nipinlẹ Borno, nibi to ti fẹẹ lọọ ta awọn ohun ija oloro naa si lọwọ ti tẹ ẹ. Inu apo ṣaka nla kan bayii lo ko awọn ọta ibọn naa si, to si tun ko ẹja gbigbẹ ati ede le e lori, kawọn agbofinro ti wọn ba fẹẹ yẹ ẹ wo ma baa mọ ohun to wa ninu apo ṣaka naa.

Loju-ẹsẹ ti wọn fọwọ ofin mu un  lo ti bẹrẹ si i ka pe oun nikan kọ loun wa nidii iṣẹ to lodi sofin ọhun. O ni ọrẹ oun kan, Sajẹnti Daihatu Murtala, toun naa jẹ ṣọja ni Jos, nipinlẹ Plateau, lawọn jọ maa n ṣiṣẹ ti ko bofin mu ọhun nigba gbogbo. O fi kun un   pe nitori pe Sajẹnti Murtala, wa nidii ohun ija oloro naa lo ṣe rọrun fawọn lati maa ji wọn ko, tawọn aa si lọọ ta a fawọn agbebọn atawọn ọbayejẹ ẹda gbogbo ti wọn nilo rẹ lati maa fi da alaafia ilu laamu.

Bo ṣe pari ọrọ ẹ ni wọn ti lọọ fọwọ ofin mu Murtala lagbegbe Baga, niluu Jos, toun naa si ti wa lahaamọ ileeṣẹ ologun orileede yii bayii.

Atẹjade kan tileeṣẹ ologun orileede yii fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lo ti sọ pe, ‘‘Loootọ ni ọwọ ti tẹ Sajẹnti Murtala ati ọrẹ rẹ, Sajẹnti Adamu, awọn mejeeji jẹ ṣọja nileeṣẹ ologun orileede yii, ni ‘3 Division’, niluu Jos, nipinlẹ Plateau. Wọn n ji ọta ibọn atawọn ohun ija oloro mi-in lọọ ta fawọn ọdaran ni, obitibiti ọta ibọn la ba lọwọ Adamu lasiko to n ko o lọ siluu Borno, fawọn onibaara rẹ.

‘’A maa too ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ta a si maa fiya to tọ jẹ awọn mejeeji basiko ba to’’.

Leave a Reply