Aṣita ibọn pa eeyan mẹfa lasiko ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n’Ileṣa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Bo tilẹ jẹ pe eeyan marun-un nileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ti gbẹmi mi ninu wahala to n ṣẹlẹ lọwọ niluu Ileṣa, sibẹ, awọn araalu sọ pe o kere tan, eeyan mẹjọ lo ti ku.

Alẹ ọjọ Aje,  Mọnde, la gbọ pe wahala naa bẹrẹ nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun igun meji ọtọọtọ kọju ija siraa wọn, ti wọn si n yinbọn lakọlakọ.

Awọn agbegbe Idasa, Ilọrọ ati Ọṣun Ankara, niluu Ileṣa, ni awọn eeyan naa ti doju ibọn kọ ara wọn, ti eeyan mẹjọ si ti jẹ Ọlọrun nipe nipasẹ rẹ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Ave ni wọn wa si ilu Ileṣa lati ọkan lara awọn ilu amulegbe wọn, ti wọn si wọya ija pẹlu awọn ti wọn n jẹ Ẹiyẹ.

Lara awọn ti wọn ku ọhun, a gbọ pe awọn mẹfa ni aṣita ibọn (Stray bullet) ba, nigba ti awọn meji jẹ ara wọn.

Gẹgẹ bi ẹnikan to n gbe agbegbe naa ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣe sọ, o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn Ẹiyẹ ni wọn kọkọ huwa buburu si awọn Ave, to si jẹ pe ṣe lawọn yẹn fẹẹ gbẹsan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe eeyan marun-un lo ti ku ninu iṣẹlẹ to bẹrẹ lalẹ ọjọ Mọnde ọhun.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe awọn ọlọpaa ti lọ si gbogbo ibi tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lati le ṣeto aabo fun ẹmi ati dukia awọn araalu.

Leave a Reply