Aṣiwaju ni iran Yoruba jẹ, a ko si gbọdọ ja awọn ẹya to ku kulẹ – Ọọni Ogunwusi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Arole Oduduwa to tun jẹ Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti sọ pe iran Yoruba kaakiri agbaye gbọdọ wa niṣọkan lasiko yii lai fi ti ẹsin tabi oṣelu ṣe.
Lọjọ Iṣẹgun ni Ọọni Ogunwusi sọrọ naa lasiko to n ṣe ayẹyẹ iranti ọdun kẹfa to gun ori-itẹ awọn baba nla rẹ
O ni abinibi ni ipo aṣiwaju ti iran Yoruba wa, gbogbo awọn ẹya yooku ni wọn si n wo wọn fun idari loorekoore.
O ni ko si abula kankan ninu ọrọ iṣọkan iran yii rara, akooko yii gan-an la si nilo lati wa niṣọkan ju. Ki iran Yoruba fi igbanu kan ṣoṣo ṣọja, ki wọn ma si faaye gba ọrọ oṣelu, ẹsin tabi awọn nnkan miran ti ko nitumọ lati raaye laarin wọn.
Kabiesi fi kun ọrọ rẹ pe, “Ninu ohun gbogbo ti a ba n ṣe, a gbọdọ ni i lọkan pe oju awọn ẹya to ku wa lara wa, a ko si gbọdọ ja wọn kulẹ, paapaa ni awọn ikorita ti wọn ti n reti iwa adari lọdọ wa.”
Ọọni ṣalaye pe ọdun mẹfa iṣejọba rẹ jẹ ojurere Ọlọrun, o ni o kun fun oniruuru ipenija, ṣugbọn ti ifẹ ati ifọwọsowọpọ awọn eeyan ilu Ileefẹ ṣẹgun rẹ.
O ni ‘Ẹẹfa’ ki i ṣe onka lasan, a le fi we ‘Ìfà’ (Freebie) ninu ede Yoruba, to si jẹ pe gbogbo eeyan ni wọn fẹ Ifa. O ni oun ko ni i sinmi rara ninu erongba oun lati tubọ mu igbe aye to nitumọ ba awọn araalu.
Laaarọ oni ni ẹgbẹ awọn Kristiẹni ati ti awọn Musulumi ti lọọ ṣadura fun kabiesi laafin.
Lara awọn lọbalọba ti wọn wa nibi eto naa ni Olu ti Ilaro, Ọba Kehinde Adegbenle, Ewi ti Ado-Ekiti, Ọba Rufus Adeyẹmọ Adejugbe, Alara ti Ilara-Ẹpẹ, Ọba Fọlarin Ogunsanwo, Ajero ti Ijero-Ekiti, Ọba Joseph Adewọle, Ọrangun ti Oke-Ila, Ọba Abọlarin Aroyinkẹye, Oore ti Ọtun-Ekiti, Ọba Adekunle Adeagbo, Obaro ti Kabba, Ọba Solomon Owoniyi, Ọlọyẹ ti Ọyẹ-Ekiti, Ọba Oluwọle Ademọlaju, Olojudo ti Ido-Fabọrọ, Ọba Ayọrinde Ilọri ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Adari agba ajọ NTDC, Fọlọrunṣọ Coker ni Aṣiwaju Ahmed Tinubu ran sibi eto naa, nibẹ la tun ti ri Iyalaje Oodua Worldwide, Princess (Dr.) Toyin Kọlade ati Mọremi ilẹ Yoruba, Oloye Iyaafin Olufunṣọ Amosun.

Leave a Reply