Aṣọ ṣọja lawọn eleyii ko sọrun, bẹẹ ogbologbo adigunjale ni wọn

Faith Adebọla

Akolo awọn ọlọpaa lawọn ọkunrin meji yii wa lasiko yii, Ọgbẹni Yahaya Armayau, ẹni ọdun marundinlogoji, ati ekeji rẹ, Bashir Isiyaku, ẹni ọdun mejilelọgbọn, aṣọ ṣọja lawọn mejeeji wọ bii ẹni pe ṣọja ilẹ wa ni wọn loootọ, ṣugbọn afurasi adigunjale ni wọn, ọwọ si ti tẹ wọn.

Alaye ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Katsina ṣe nipa wọn lọjọ Abamẹta, Satide, nigba ti wọn ṣafihan wọn fawọn oniroyin ni pe niṣe lawọn ayederu ṣọja yii n fi imura wọn jale, wọn n gba ọkada, wọn tun n gba owo lọwọ awọn araalu, bẹẹ ni wọn n fi ankọọfu sọwọ awọn ti wọn ba ha si wọn lọwọ, wọn si n fiya jẹ wọn.

Bashir, ti inagijẹ rẹ n jẹ Ṣọja, ati Yahaya, tawọn eeyan mọ si Kofur, jẹ ọmọ bibi abule Yar-Kaware, nijọba ibilẹ Kafur, nipinlẹ Katsina.

Ọga ọlọpaa naa ni ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii lọwọ palaba awọn mejeeji segi, lasiko ti wọn fipa gba ọkada Bajaj Ọgbẹni Yau Zaharadin, ti wọn si tun gba ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ ẹlomi-in ni abule Sheka, nipinlẹ naa.

O ni iwadii fihan pe lati bii oṣu diẹ sẹyin lawọn ọdaju ẹda yii ti n han awọn araalu leemọ, wọn lawọn funra wọn jẹwọ pe ọkada mẹrin lawọn ti gba l’Abuja, kawọn too sa kuro nibẹ nigba tawọn eeyan fẹẹ maa fura pe awọn ki i ṣe ṣọja gidi, ati pe awọn n mura lati sa kuro ni Katsina lọwọ fi ba wọn yii.

Nigba tawọn ọlọpaa lọọ tu ile wọn, wọn ba awọn nnkan eelo ṣọja, ati aṣọ ọlọpaa olokun meji, ankọọfun meji, ibọn, fila bẹntigọọ ọlọpaa, bata ati ṣokoto ṣọja, awọn afurasi naa ni rira lawọn ra wọn, wọn lọrẹẹ awọn kan lo ba awọn ra awọn ẹru ofin yii.

Ṣa, iwadii ti bẹrẹ lori wọn, wọn lawọn mejeeji ati ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o lọwọ ninu iṣẹẹbi wọn yoo kawọ pọnyin rojọ laipẹ.

Leave a Reply