Aṣọ ni Heritage, akẹkọọ Fasiti Ifẹ, fẹẹ sa to fi ja sinu sọkawee, o ti ku ki wọn too ri i yọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Akẹkọọ ọlọdun keji ni ẹka Linguistic and African Language ni Fasiti Ifẹ, Ajibọla Heritage Ayọmikun, ti pade iku ojiji lasiko to ja sinu sọkawee kan nileegbe aladaani to wa ninu ọgba naa.

Gẹgẹ bi akẹkọọ kan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣe sọ fun ALAROYE, ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lasiko to fẹẹ sa aṣọ to fọ, to si tẹ ori pako ti wọn gbe sorii sọkawee naa.

Ilegbee ti wọn n pe ni BVER niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, bi Heritage ṣe gbẹsẹ le pako yii lo ja sinu sọkawee ọhun, kia si lawọn akẹgbẹ rẹ ti figbe bọnu, ti awọn kan si lọ ke si awọn alaṣẹ.

 

Nigba to n srọ nipa iṣẹlẹ naa, Alukoro Fasiti Ifẹ, Abiọdun Ọlarewaju, sọ pe bi awọn alaṣẹ ṣe gbọ ni ọga agba fasiti naa funra rẹ, Ọjọgbọn Eyitọpẹ Ogunbọdẹde, ṣaaju awọn eeyan lọ sibẹ.

Ọlarewaju sọ siwaju pe odidi wakati kan ni awọn ajọ panapana fi ṣiṣẹ ki wọn too ri Heritage gbe jade, ṣugbọn nigba ti wọn gbe e deleewosan OAUTHC lawọn dokita sọ pe o ti ku.

O ni Ojọgbọn Ogunbọdẹde ba awọn akẹkọọ kẹdun iku akẹgbẹ wọn ọhun, bẹẹ lo si tun ba awọn obi oloogbe daro.

Ni bayii, awọn alaṣẹ OAU ti ṣeleri pe awọn yoo ṣewadii iku ojiji to pa akẹkọọbinrin naa, bẹẹ ni awọn yoo si fiya to tọ jẹ ẹnikẹni to ba lọwọ ninu ẹ.

 

Ogunbọdẹde tun parọwa si awọn akẹkọọ lati ṣe suuru, ki wọn si faaye gba awọn ọlọpaa lati ṣiṣẹ wọn bo ti yẹ lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply