Aṣiṣe nibọn wa to pa ọmọ ọdun meji n’Ilaro- Awọn aṣọbode

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa, ẹka ‘Ogun 1 Area Command’, ti ni awọn kabaamọ iṣẹlẹ ibọn yinyin to pa ọmọ ọdun meji kan n’Ilaro, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu yii, eyi tawọn oṣiṣẹ awọn kan yin, to si lọọ ṣeeṣi ba ọmọbinrin naa.

Agbẹnusọ awọn aṣọbode naa lẹka yii, Ahmed Oloyede, sọ ọ di mimọ pe inu ibanujẹ gbaa ni kọmandi awọn wa bayii nipinlẹ Ogun lori iṣẹlẹ yii. O ni ọga awọn pata ti lọọ ṣabẹwo sile awọn obi ọmọdebinrin naa lati ba wọn kẹdun, o si ka awọn lara gan-an pe aṣita ibọn pa ọmọ naa. O fi kun un pe awọn oṣiṣẹ awọn to yinbọn ko deede yin in, ẹnu iṣẹ ni wọn wa, ko si ki i ṣe pe wọn doju ibọn kọ ọmọde, aṣiṣe ni.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an ni pe l’Ọjọbọ naa ti i ṣe ọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni ọdun yii, awọn kọstọọmu yii n le ọkunrin kan ti wọn fura si pe irẹsi ilẹ okeere lo ko wọlu, wọn le e de agbegbe Itawaya, nitosi Poli Ilaro, nigba naa ni wọn si bẹrẹ si i yinbọn.

Ibọn ti wọn yin naa lo ba ọmọ ọdun meji yii labiya, to wọnu ara rẹ, to si pada ran an sọrun ọsan gangan.

Iya ọmọ naa paapaa fara gbọta ba a ṣe gbọ, ati ọkunrin kan naa toun pẹlu n re kọja lọ lasiko naa.

Wọn ṣaajo ọmọde tibọn ba, wọn gbe e lọ sọsibitu, ṣugbọn awọn dokita sọ pe ọmọ naa ti dagbere faye.

Ni ti ẹni ti wọn fura si pe o ko irẹsi wọlu, nigba ti wọn tu ẹru rẹ wo ni wọn ri i pe ki i ṣe irẹsi lọkunrin naa ko, ko si lẹbọ lẹru bo ti wu ko kere mọ.

Ohun to ṣẹlẹ yii ko ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ gẹgẹ bawọn olugbe agbegbe yii ṣe wi. Wọn ni ọpọ igba ni alaiṣẹ ti rọrun ojiji nitori irẹsi ilẹ okeere tawọn kọsitọọmu n wa kiri yii, bo ba si ṣẹlẹ tan, ko si kinni kan ti yoo ti ẹyin rẹ yọ.

Ṣugbọn ni ti eyi to ṣẹlẹ yii, awọn aṣọbode naa tọrọ aforiji, wọn si ni iwadii ti bẹrẹ lori ẹ pẹlu.

 

Leave a Reply