Aṣiri tu pata: Eyi ni iye eeyan tawọn ṣọja yinbọn pa ni Lẹkki

Wọn ko mọ pe ẹnikẹni ri awọn, ṣugbọn awọn eeyan ri wọn, nitori aye ti yatọ si tatijọ. Wọn ri ọkọ agbarigo meji to jẹ tawọn ṣọja to n jade ni baraaki awọn ologun ti wọn n pe ni Bonny Camp. Awọn ṣọja kun inu ọkọ naa fọfọ, beeyan si ri wọn, yoo mọ pe ibi ijangbọn kan ni wọn n lọ. Bi ko jẹ awọn ni wọn n lọọ bẹrẹ ijangbọn naa, yoo jẹ wọn n lọọ da si ijangbọn kan to ti wa nilẹ ni, nitori ṣọja ki i lọ sode suuru kan, afi ode jagidijagan. Bi mọto naa ti jade ni wọn fidio ẹ, wọn si fi fidio ọhun tẹle wọn titi ti wọn fi jade si Opopona ti wọn n pe ni Ozumba Mbadiwe Street, ni adugbo Victoria Island, l’Ekoo, ṣe siriiti yii lo fori sọ Dodan Barack yii, beeyan ba si duro siwaju baraaki awọn ṣọja yii, siriiti ti yoo maa wo iwaju rẹ labẹ biriiji nibẹ, Ozumba Mbadiwe ni. Siriiti ti mọto awọn ṣọja mejeeji dori kọ ree, tawọn mọto mejeeji si n lọ lẹlẹẹlẹ.

Ni deede aago mẹfa kọja iṣẹju mọkandinlọgbọn lawọn mọto yii jade o, ọjọ ṣẹṣẹ n bora diẹdiẹ ni, ilẹ n ṣu bọ, aago mẹfa aabọ irọlẹ ku iṣẹju kan. Bi awọn mọto yii ti n rin lọ, bẹẹ ni awọn ajọ ajafẹtọọ-agbaye, Amnesty International, fi ẹrọ igbalode tẹle wọn, bo tilẹ jẹ oju kan bayii lawọn jokoo si, sibẹ, wọn n ri awọn mọto yii bi wọn ti n lọ. Ori irin ti wọn wa yii ni awọn mọto bii tiwọn meji mi-in ti tun dara pọ mọ wọn, ni mọto awọn ṣọja yii ba di mẹrin, wọn si tẹle ara wọn lẹyin, wọn n lọ.  Bi wọn ti n tẹle ara wọn lọ yii, wọn kọja niwaju ileeṣẹ to n ṣoju awọn orilẹ-ede wọn, iyẹn awọn ẹmbasi loriṣiiriṣii.  Wọn kọja niwaju Ẹmbasi Australia ati Ẹmbasi Japan. Nigba naa, wọn ko ya sọtun-un wọn ko ya sosi mọ, lori titi Ozumba Mbadiwe yii ni wọn wa ti wọn n ba lọ, ṣe titi naa lo fori sọ Too-geeti (Toll-gate) Lẹkki.

Ni bii iṣẹju mẹẹẹdogun lẹyin eyi ni fidio naa tun gbe mọto awọn ṣọja yii, mọto naa si ti di mẹfa bayii, nigba tawọn meji mi-in tun darapọ mọ wọn, ẹni kan ko ri wọn. Ṣugbọn mọto ti di mẹfa, mọto awọn ologun, wọn si n lọ si Too-geeti yii. Ni Too-geeti yii, awọn eeyan ti jokoo lọ rẹpẹtẹ ni tiwọn, ọdọ ni gbogbo wọn, wọn ko si mu ohun ija kankan bayii dani, abẹla ati awọn nnkan to le riran mi-in ni wọn n lo, nitori lojiji ni wọn kan ri i pe wọn ti mu ina gbogbo agbegbe naa lọ.  Ina gbangba kan ti i maa a riran nibẹ, wọn ti pa a, nigba ti yoo si fi di bii aago meje, agbegbe naa ti ṣokunkun dudu. Asiko ko-ri-ni-ko-mọ-ni yii ni awọn ṣọja to wa ninu mọto mẹfa yii bọ silẹ ninu ọkọ wọn, wọn ko si ba ẹnikẹni sọrọ ninu awọn ti wọn n ṣewọde yii, wọn kọ lu awọn ọdọ naa tijatija nitori niṣe ni wọn doju ibọn kọ wọn.

Bi wọn ti n yin wọn nibọn, bẹẹ ni ọrọ di bo o lọ o yago, kaluku bẹrẹ si i sa asala fun ẹmi ẹ, nitori titi di asiko naa, niṣe ni kaluku wọn ro pe ko si ṣọja tabi agbofinro kan ti yoo doju ibọn kọ awọn ero to to bayii, bi wọn yoo ba tilẹ ṣe kinni kan fawọn, wọn yoo kọkọ gbọ tẹnu wọn na. Ṣugbọn awọn ṣọja ti wọn wa ko ba alaye kankan wa, wọn wa pẹlu ija rẹpẹtẹ ni, ija naa ni wọn si gbe ko awọn eeyan yii loju, ti wọn dana ibọn fun wọn. Bi wọn ti n ṣe iṣẹ buruku yii, bẹẹ ni awọn kọọkan ti wọn ribi duro si n ya fidio awọn ṣọja naa, ti wọn si n pariwo, ti wọn si n ṣalaye bi wọn ti n pa awọn eeyan to, ati bi awọn ṣọja ṣe doju ibọn kọ awọn. Fidio yii lo lọ kiri kari aye, ti gbogbo eeyan si n beere pe iru awọn ṣọja wo lo wa ni Naijiria yii, ti wọn n doju ibọn kọ awọn ọdọ, iro ibọn naa si n wọ inu fidio naa, gbogbo aye lo n gbọ ‘tako-tako’ ibọn wọn.

Nigba ti awọn ṣọja yii lọ tan lẹyin ti wọn ti paayan silẹ, adugbo naa da paro, ṣugbọn awọn kan ninu awọn ti wọn n ṣewọde naa tun pada sibẹ, ko si tun pẹ ti awọn agbofinro fi le awọn yii naa lọ. Nigba ti ilẹ mọ ni ọjọ keji, ti awọn araalu n pariwo pe awọn ṣọja ni o, awọn ṣọja taku, wọn ni ko si ohun to jọ bẹẹ, ki lawọn yoo wa lọ sibi ti wọn ti n yinbọn. Wọn ni awọn kọ o. Awọn eeyan bẹrẹ si i gbe e kaakiri pe ogunlọgọ awọn eeyan lo ku, pe wọn ti pa awọn eeyan pupọ o, ṣugbọn ọpọ awọn eeyan ko fẹẹ gba ọrọ naa gbọ rara, nitori wọn ko ri oku awọn eeyan rẹpẹtẹ loootọ, wọn ko si ri awọn eeyan nilẹẹlẹ ti wọn n joro iku, yatọ si awọn meji mẹta kan ti wọn ti fi fidio ya nigba ti kinni naa n ṣẹlẹ lalẹ, ko tun si ẹni to tete mọ ohun to ṣẹlẹ. Awọn ajafẹtọọ-ọmọniyan, Amnesty International yii, lo kọkọ kede pe yoo to awọn eeyan mẹrindinlọgọta to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ṣugbọn ko sẹni to fẹẹ gba wọn gbọ, nitori wọn o ri oku awọn eeyan loootọ. Ọmọbinrin oṣere kan ti wọn n pe ni DJ Switch (Obianuju Catherin gan-an lorukọ ẹ), lo kọkọ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ nibẹ fun gbogbo aye, nitori bo tilẹ jẹ pe oun naa wa nibi iṣẹlẹ yii, ko kuro nibẹ titi ti awọn ṣọja fi pa awọn ti wọn pa, to si tun sa jade nibi to sa pamọ si, to lọọ ba ọga awọn ṣọja naa, to si beere lọwọ ẹ pe ki lo de ti wọn n pa awọn. Ọmọbinrin yii ati awọn diẹ ninu wọn gbe oku awọn ti wọn pa yii, wọn si gbe wọn siwaju awọn ṣọja naa. Awọn ṣọja yii ko ṣe meni wọn ko ṣe meji, wọn yaa ko awọn oku naa, wọn rọ wọn da sinu mọto wọn, wọn si ko gbogbo wọn lọ. Nitori bẹẹ, ni ọjọ keji ti DJ Switch ṣalaye fun gbogbo aye pe awọn eeyan ku nibẹ gan-an, ẹrin lawọn ṣọja n fi i rin, wọn ni bi eeyan ba ku nibi iṣẹlẹ naa, ko gbe oku wọn jade.

Ori fidio lọmọbinrin olorin naa ti n ṣe gbogbo eleyii, o si sọ pe kinni naa ko ṣe ẹyin oun, oju oun lo ṣe, gbogbo oku to ku ti wọn n wi yii, awọn ṣọja lo ko wọn lọ. O ni lẹyin ti awọn ṣọja ti lọ tan paapaa, awọn ọlọpaa adugbo naa wa, awọn ni wọn ṣẹṣẹ waa pari ọrọ naa. Koda, awọn SARS ti wọn n tori ẹ ja naa wa sibẹ, awọn naa si tun ba wọn ṣe ninu iṣẹ naa.  Ọmọbinrin yii ni oku sun loootọ, oun si le fi Ọlọrun bura. Ṣugbọn koko to wa nibẹ ni pe ko si oku kan nilẹẹlẹ, ọrọ naa si ka gomina ipinlẹ Eko lara ti oun naa fi sọ pe ki wọn yee sọ ohun ti ko ṣẹlẹ, bi oku ba ku, tabi to ba jẹ ṣọja yinbọn ni, gbogbo aye ni iba foju ri iye oku to ku. Lọjọ keji to sọ eyi lo tun pada wa, o ni awọn eeyan meji pere lo ku, ẹni kan ku soju ija yii, ẹni keji ku si ọsibitu. Sibẹ DJ Switch ni irọ to n purọ funrọ ni, awọn eeyan to ku ju bẹẹ lọ.

Lẹnu ibi ti oun ti n ba wọn fa ọrọ yii lọwọ, nibẹ ni Amnesty International ti gbe iwadii wọn jade. Iwadii yii fihan pe loootọ ni awọn ṣọja lọ si Too-geeti, wọn si yinbọn nibẹ, ki wọn yee purọ kan fun wa. Nigba naa ni awọn ṣọja jade ti wọn si jẹwọ, wọn sọ ootọ kan, wọn si fi irọ bii marun-un bo ootọ naa mọlẹ. Wọn ni loootọ lawọn lọ si too-geeti Lẹkki yii nigba ti awọn ijọba ipinlẹ Eko ranṣẹ sawọn, ṣugbọn ko si ẹmi ẹnikan to ti ọwọ awọn bọ, nitori awọn ko yinbọn ẹyọ kan bayii nibẹ. Wọn ni gbogbo eyi ti wọn n ri yẹn, ti awọn eeyan n gbe sori fidio ati ikanni wọn, ofuutufẹẹtẹ lasan ni, nitori bi awọn ba yinbọn nibẹ, oku yoo pọ rẹpẹtẹ ni o. Wọn ni ẹni to ba ri oku awọn eeyan to ku nibẹ ko gbe e jade, bi awọn ba ti ri oku yii, nigba naa ni awọn yoo le wadii ẹni to pa wọn. Ṣugbọn bi ko ba si oku ko si ọrọ, irọ lawọn eeyan n pa mọ awọn.

Nigba naa ni awọn oniroyin ileeṣẹ iwe iroyin Premium Times to jẹ ti ori ẹrọ ayelujara jade, wọn gbe iṣẹ iwadii nla dide, iwadii naa lo si tu aṣiri ọpọlọpọ nnkan tẹni kan ko mọ, o si fi han pe loootọ lawọn ṣọja paayan, ati pe iye awọn ti wọn pa yoo le ni aadọta daadaa. Bẹẹ ọdọ ni gbogbo wọn. Sodiq Adeoye to n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ oniwadii kan, SBM Intelligence, lo sọ fun ọkan ninu awọn oniroyin Premium Times pe awọn araadugbo awọn olowo ti wọn n pe ni Admiralty Way sọ pe awọn ri oku to lefoo soju omi lẹyinkule awọn, awọn si fura pe oku naa le jẹ lara awọn ọdọ to ku si Too-geeti Lẹkki yii, ṣe Admiralty Way ti wọn n wi yii, iwaju too-geeti yii gan-an lo wa, bii kilomita meji sibẹ ni.

Eti were ni ti ekute ile, ilakọsin o ni i gbọ ohun ọmọ rẹ ko duro, abiyamọ ki i gbọ ẹkun ọmọ rẹ ko ma ta eti were, bi oniroyin ba ti gbọ finrin nibi kan, iṣẹ de niyẹn. Kia ni Premium Times gbe awọn eeyan dide, ni wọn ba lọ si adugbo naa, ohun ti wọn ri nibẹ si ya wọn lẹnu. Ni bii aago mẹfa aarọ ni Deji Aṣiru, ti ileeṣẹ iwe iroyin naa gbera, lo ba kọri si ibi ti wọn ti ri oku to lefoo loju omi. Wọn gba odidi ọkọ oju omi kan, wọn ni ko gbe awọn yipo ibẹ, ki wọn le mọ ibi ti oku naa ti lefoo gan-an. Bi wọn ti n lọ loju omi yii, oniroyin naa ri awọn ile gẹrẹjẹ gẹrẹjẹ kan, awọn ile onipako ti wọn maa n kọ si eti okun, ile naa si pọ diẹ, abule kekere ti awọn apẹja ati ọlọkọ oju omi n gbe ni. Abule yii wa lori omi nibẹ, lẹyin otẹẹli kan ti wọn n pe ni Oriental Hotel. Ẹyin Too-geeti Lẹkki yii gan-an ni abule awọn apẹja yii wa, bi eeyan ba n bọ lati ọna Victoria Island wa si Lẹkki ni yoo ri i daadaa.

Bi akọroyin yii ti ri i ni ọkan ẹ sọ fun un pe ko si bi iru iṣẹlẹ bayii yoo ti ṣe ṣẹlẹ ti awọn ara abule ori omi yii ko ni i mọ, paapaa nigba to jẹ ẹyin Too-geeti ti iṣẹlẹ naa ti waye ni wọn n gbe. Lo ba ni ki ẹni to gbe wọn ninu ọkọ oju-omi naa ya sibẹ. Bi wọn ti debẹ, afi bi igba ti awọn ara ileto yii ti n reti ẹni ti yoo waa gbọ tẹnu wọn ni. Ko ma ti i beere rara ni, awọn eeyan naa bẹrẹ si i tu kẹkẹ ohun to ṣẹlẹ ati eyi ti wọn foju ri fun un. Boya ohun to n ka awọn ara abule yii lara ni pe ninu awọn naa ti wọn ko si ni oju ija fi ara gba ọta ibọn. Awọn gan-an ni wọn kọkọ fi ẹṣẹ ọrọ ti obinrin DJ Switch n sọ mulẹ pe loju awọn lo ṣe korokoro, awọn ri awọn ṣọja ti wọn n gbe oku awọn ti wọn pa sinu mọto wọn, ti wọn si ṣe bẹẹ wa wọn lọ. Bi wọn ti beere pe ṣe loootọ lawọn ṣọja paayan nibi, ẹni kan dahun fara, “Haa, gbogbo awa ti a wa nile la riyẹn, ṣebi ẹni kan wa to jẹ oju wa nibi ni wọn ṣe yinbọn pa a, ti wọn si gbe oku ẹ lọ!”

Ẹni kan ninu awọn ara aba naa to n jẹ Ray ni, “Ẹ wo o, orilẹ-ede mi niyi, ko si ibi ti mo fẹẹ sa lọ, bi wọn ba fẹẹ waa gbe mi ki wọn tete maa bọ. Ohun ti awọn ṣọja ati ọlọpaa ṣe nibi lọjọ yẹn buru o. Abi kin ni wọn maa waa yinbọn lu wa si nigba ti a n ṣe iwọde wọọrọ!” Wọn beere lọwọ Ray pe ṣe o ri oku awọn eeyan, o ni, “Daadaa, mo ri oku rẹpẹtẹ, ṣebi awọn ṣọja yii ni wọn waa fi mọto wọn ko wọn lọ! Ki lo de ti Sanwoolu gan-an n purọ! Ṣebi lọjọ iṣẹlẹ yii, oun naa sare wa laaarọ ki ilẹ too mọ, ṣebi o ṣi ri oku awọn eeyan nilẹ nibẹ! Ki lo wa n sọ pe ko sẹni to ku si.” Awọn araadugbo mi-in naa da si i, awọn yii ni wọn si ṣalaye pe lẹyin ti awọn ṣọja ti lọ, awọn ọlọpaa de, awọn ọlọpaa agbegbe Victoria Island nibẹ, Ganiyu si ni DPO to ṣaaju wọn jẹ, awọn ni awọn mọ ọn daadaa. Wọn ni Ganiyu yii naa ati awọn eeyan rẹ yinbọn pa awọn kan nigba ti wọn wa.

Awọn ara aba yii ni wọn ṣalaye bi ọrọ naa ti ri gan-an. O ni lọdọ awọn ni pupọ ninu awọn ti wọn n ṣe iwọde na sa wa nigba ti ariwo ibọn bẹrẹ, ibọn si ba ọpọlọpọ wọn. Koda, obinrin kan ni ninu ibi ti oun wa nibẹ, ibọn ba ọmọ oun naa lapa, o si fi apa rẹ han awọn oniroyin, bẹẹ ni awọn mi-in ko ajoku ọta ibọn ti wọn ri lọdọ wọn nibẹ jade. Wọn ni awọn mi-in sa wọnu omi lọ ni, to si jẹ wọn ko jade laaye, bẹẹ ni ọta ibọn ti ba awọn mi-in ki wọn too de ọdọ awọn rara. Wọn ni awọn ṣe iranlọwọ fun awọn ti awọn le ṣe e fun, ọkunrin apẹja kan to si n jẹ Agboọla Kapko sọ fawọn Premium Times yii pe ọkọ oju omi loun fi n ko ọpọ eeyan sọda si odikeji nibi ti wọn ti le ribi ba sa lọ, bẹẹ ọpọ ninu awọn yii ti fara gbọta.

Kapko nawọ si ọọkan bayii, o ni “Ibi ti emi wa niyẹn nigba ti wọn bẹrẹ si i yinbọn ni too-geeti, n lawọn eeyan ba bẹrẹ si i sare ko somi. Mi o le fi wọn silẹ bẹẹ, nitori ẹ ni mo ṣe sun mọ wọn ti mo n fa awọn ti wọn ba ti fẹẹ ri jade kuro ninu omi, ti mo si n fi ọkọ mi gbe wọn lọ si apa ibomi-in, ti awọn mi-in si n ba ibẹ sa lọ ni tiwọn.” Iyawo Kapko gan-an fi ẹsẹ ẹ to wu han, o ni nibi ti oun ti n sare lọ nigba ti ibọn bẹrẹ si i ro, ti ọta ibọn naa si n wọ ọdọ awọn ni oun ti ṣubu lulẹ, ti oun si fi ẹsẹ ṣeṣe. Ohun to mu ọrọ naa yanju lati ọdọ awọn eeyan yii ni pe gbogbo wọn lo ri oku, wọn ri awọn ṣọja ti wọn yinbọn pa wọn, wọn ri awọn ọlọpaa to pada waa palẹ to ku mọ, ti wọn si tun yinbọn pa awọn mi-in, wọn ri awọn SARS funra wọn ti wọn wa, wọn si ri i bi wọn ti rọ oku sinu mọto kaakiri. Awọn yii fi ẹsẹ rẹ mulẹ pe ki ẹnikẹni ma sọ pe ko sẹni to ku nibi iṣẹlẹ yii mọ o, nitori awọn oku ti wọn ku ko niye. Tabi ṣe awọn ti wọn ku somi leeyan yoo sọ ni tabi ti awọn ti wọn yinbọn pa.

Ọrọ yii gan-an fẹẹ da wahala silẹ laarin awọn ṣọja ati ijọba Eko. Ijọba Eko ti gbe igbimọ kan dide lati wadii ohun to ṣẹlẹ gan-an, ati lati mọ bi awọn eeyan ti ku to loootọ, bo ba si jẹ awọn eeyan ku rẹpẹtẹ bẹẹ, nibo ni wọn ko wọn si. Olobo ta awọn igbimọ yii pe bi wọn ba fẹẹ mọ ibi ti awọn ṣọja ko awọn eeyan naa si, ki wọn lọ si ile igbokuu-si awọn ṣọja gan-an, o ṣee ṣe ki wọn ba wọn nibẹ. Ki ọrọ ma di pe awọn ṣọja yoo ti tun ko awọn eeyan naa kuro ni moṣuari wọn ni wọn ṣe ja lu wọn lojiji ni ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii. Wọn ni ki wọn jẹ ki awọn wo mọṣuari wọn. Ṣugbọn awọn ṣọja ẹnu ọna yari, wọn ni awọn ko le jẹ ki wọn wọle, koda, awọn yoo yinbọn fun wọn ti wọn ko ba tete kuro niwaju awọn. Gbogbo alaye ti awọn ọmọ igbimọ to lọ si Ọsibitu awọn ṣọja n’Ikoyi yii ṣe ko wọ ẹnikẹni leti, wọn le wọn tefetefe.

Lẹyin ọpọlọpọ arọwa ati ọrọ suuru ti ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ naa, Ẹbun Olu-Adegboruwa, sọ ni wọn too gba wọn laaye lati wọ ibẹ.

Kinni kan ti fidi mulẹ bayii ṣaa o, iyẹn naa ni pe gbogbo aye ti mọ, awọn ṣoja naa ti mọ, ijọba ti mọ, pe awọn ṣọja paayan ni Too-geeti Lẹkki, ati pe iye awọn ti wọn pa ki i ṣe kekere rara. Ohun ti yoo wa ṣẹlẹ lati ọdọ awọn alagbara agbaye ti wọn gbeja awọn ọdọ ti wọn yoo si fiya jẹ awọn ologun to ba pa araalu lai nidii, ati ohun tijọba Naijiria funra wọn yoo ṣe, lo ku ti gbogbo aye n reti bayii o.

5 thoughts on “Aṣiri tu pata: Eyi ni iye eeyan tawọn ṣọja yinbọn pa ni Lẹkki

  1. Ero temi nipe ti won ba mu tinubu ati sanwolu oro aniyaju…… Idinipe gbogbo ihale ti awon soja khaale mo awon eyan won yi pe enitoba yoju ninu wonpe eyan ounku awon mapawon ni ijoba ma mu won ni…… Tinubu loko won ni oro naa so tori ika akeke ejo oloro niwon

    Tinubu de pada lati ibi tosalo itiju pe wonle danu loun ounparo pe ounkolo ibikan, nigba toma tun yoju sibe pelu sanwolu loba ni

    Kini won wa de ibiti won ni wonti yinbo?
    Talo ran won wa? awon wo ni won nfun won lounje? Awon oluwode naa ni ejoje, ejowo se iwaju ile babababa tinubu nibiti a won oluwode pejosi, lonse nbere ibere amukunmoeko, ibere were

    Eripe tinubu ti gbonju loju ara e ki ashiri oro maba tu ni, abi sebi nitori ki enikan maba yoju ni, bi awon soja se ndunkoko ni tinubu naa ndunkoko,

    Sanwolu oniro ayie oun orun , bi baba isale koba fun ni amoran koni ilese soja, osini ou o mo bi won se debe nigbati eyi tiwonpe ni buhari fun wa o gbe phone bi oti gbiyaju to,

    Awon soja wa soro sita pe sanwolu lokan si awon fun iranlowo losetun wan nso nka mi

  2. Ajë ke lana ömö leni ni örönaa jë lojumi.
    Ni öjö kökandinlogun osu këwa( 19-10-2020 ) ni tinubu söpe ki awön ödö böwöfun ofin konleogbele ti ijöba eko palasë tiwön ko bafëë kandin ninu iyö. Irölë öjö isëgun tuesday si ni awön ödö kandin ninu iyö ni toll gate lekki. Se awaaripe gbangba gbangba lofojuhan pe ejo tinubu ati sanwo olu ni öwö ninu isëlë toll gate bayii?

  3. Ohun ibanuje nla ni ki majesin ku loju obi. Gbogbo iro ti awon ti a pe ni Olori wa npa nfi idi re mule pe won ko beru Olorun. Bibeli wipe e wi fun eniyan buburu pe ki yoo se RERE. Gbogbo awon ti won mo nipa iku awon omo wonyi kii yoo lo laijiya tiletile, tomotomo won. Olorun yoo gba esan Lara won. Ki Olorun tu gbogbo ebi awon to ku ninu. Ki o si gbe awon omo naa si afefe rere.

Leave a Reply