Aṣiri tu! Wọn lawọn oloṣelu lo pa Dokita Aborode, ọmọwe to n ṣiṣẹ agbẹ n’Igangan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin nnkan bii oṣu mẹta tawọn amookunṣika pa agbẹ aladaa nla kan lagbegbe Ibarapa, Ọmọwe Fatai Aborode, aṣiri awọn afurasi apaayan to gbẹmi ẹ ti tu, wọn niku ọkunrin ọmọwe naa lọwọ kan oṣelu ninu dipo awọn Fulani ti gbogbo aye n fura si lati ọjọ yii.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ, Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa ti mu baba ẹni ọgọrin ọdun kan ti wọn n pe ni Pa Ọlawuwo atawọn ẹmẹwa rẹ ti wọn fẹswun kan pe wọn lọwọ ninu iku ọkunrin naa.

O ni “Lati ijẹta la ti gbe wọn lọ si kootu, ti ile-ẹjọ si ti paṣẹ pe ki wọn fi wọn pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn titi digba ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju”

 

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kọkanla, oṣu kejila, ọdun 2020, lawọn ẹruuku lọọ ka Aborode to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Kunfayakun Green Treasures Limited, mọnu oko ẹ to wa lọna Apodun, niluu Igangan, ti wọn si ṣa a ladaa yannayanna titi to fi ku.

Ọkunrin ti wọn pa nipakupa yii lawọn ara agbegbe Ibarapa n wo gẹgẹ bii oluranlọwọ wọn, nitori bo ṣe pese iṣẹ fun ẹgbaagbeje eeyan to gba sinu oko nla to da siluu Igangan gẹgẹ bii oṣiṣẹ.

Ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti naka aleebu si awọn ọlọpaa, o ni iku Aborode lọwọ oṣelu ninu, ati pe awọn agbofinro ti mọ awọn to ṣiṣẹ ibi naa, wọn kan kọ lati mu wọn ni.

Ṣaaju igba naa, igbagbọ ọpọ eeyan ni pe awọn Fulani ni wọn pa baba naa, afi nigba ti iroyin deede lu sita pe ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ awọn to huwa ika ọhun, ati pe Yoruba ni wọn, wọn ki i ṣe awọn Fulani ti gbogbo aye foju si lara.

Nigba to n jabọ iwadii to ṣe nipa iku Aborode ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin, Gomina Makinde ṣalaye pe “ariwo ti gbogbo eeyan n pa ni pe awọn Fulani lo pa Dokita Aborode. Ṣugbọn nigba ti mo ṣabẹwo si Ibarapa, mo lọ sile baba ẹ, wọn si jẹ ki n mọ pe iku Dokita lọwọ oṣelu ninu.

“Wọn ni aiṣiṣẹ bii iṣẹ awọn ọlọpaa naa wa lara ohun to ṣokunfa iku Dokita Aborode.

“Wọn ni ẹnikan lo fi ọkada gbe e lọ soko lọjọ yẹn. Bi wọn ṣe n ti inu oko bọ lawọn eeyan yẹn da wọn duro, ti wọn si ja Dokita Abodore silẹ lẹyin ọkada to gbe e.

“Ẹni to fọkada gbe e kegbajare lọ sile fun iranlọwọ awọn eeyan.

“Awọn kan naa ti wọn n ti inu oko wọn bọ ba wọn nibẹ, wọn si gbọ bi Dokita ṣe n bẹ awọn to fẹẹ pa a ati itakurọsọ to waye laarin wọn.  Mo ni ede wo lawọn to pa a n sọ, wọn lawọn àgbẹ̀ to gbọ ọrọ ti wọn n sọ lọjọ yẹn sọ pe Yoruba ni wọn n sọ.”

Leave a Reply