Aṣiri tu, wọn ni ọmoogun ilẹ wa wa ninu awọn to n ta ibọn ati aṣọ ṣọja fawọn ajinigbe

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Zamfara, Ọgbẹni Bello Matawalle, ti sọ pe awọn agbẹyinbẹbọjẹ ati ọdalẹ kan to wa ninu awọn ọmoogun ilẹ wa wa lara ohun to fa a ti ina ọṣẹ tawọn agbebọn n ṣe lapa Oke-Ọya fi n jo geregere, ti isapa ijọba ko si mu eeso jade. Gomina ni ina naa lawo ninu ni, lo fi fẹẹ maa jo goke odo.

Gomina Matawalle, ti igbakeji ọga oṣiṣẹ rẹ, Bashir Maru, ṣoju fun lo sọ bẹẹ nibi ipade kan to ṣe laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, pẹlu awọn oniroyin lọfiisi gomina latari iṣẹlẹ awọn agbebọn ti wọn ṣakọlu lemọlemọ sawọn agbegbe kan nipinlẹ naa.

O ni laipẹ yii lọwọ awọn ọmoogun ilẹ wa tẹ ọkan lara wọn tawọn forukọ bo laṣiiri nibi to ti n ko awọn yunifọọmu sọja ati ibọn fun awọn janduku agbebọn, tawọn yẹn naa si n fun un lowo, lọwọ ti ba a. O ni ṣọja naa pẹlu ọrẹbinrin ẹ ni wọn jọọ lọwọ ninu iwa ọdalẹ naa, awọn mejeeji si ti wa lakata igbimọ oluṣewadii ileeṣẹ ologun. O ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ni wọn lo ọgbọn-inu gidi, wọn ṣiṣẹ lori olobo to ta wọn, eyi lo si jẹ ki aṣiri ọrọ naa tu si wọn lọwọ.

Bakan naa ni gomina ọhun tun sọ pe awọn agbebọn kan ti wọn n sọ pe awọn ti ronu piwada, awọn o huwa janduku mọ, ti ijọba si tẹwọ gba wọn tun ti gbọna ẹyin pada saarin awọn ara wọn to ku ninu igbo, leyii to fihan pe iṣẹ alami ni wọn n dọgbọn waa ṣe tẹlẹ.

Matawalle ni awọn iṣẹlẹ wọnyi ti fidi ọrọ kan ti gomina ipinlẹ Niger, Bello Mohammed, sọ laipẹ yii, pe ko le si aṣeyọri gidi kan lori bawọn ṣe fẹẹ ṣẹgun awọn afẹmiṣofo agbebọn, atawọn ajinigbe, ayafi tijọba ba kọkọ juwe ọna ile fun awọn kan-n-da inu irẹsi to wa laarin awọn jagunjagun ilẹ wa.

Matawalle lo anfaani naa lati dupẹ lọwọ awọn ṣọja ti wọn jẹ oloootọ, ti wọn n pe ṣe alami fawọn ọtẹlẹmuyẹ.

O lawọn n reti igbesẹ tileeṣẹ ologun maa gbe lori awọn ọdalẹ ọmoogun ti wọn n ṣakoba fun itẹsiwaju wọn.

Leave a Reply