A fara mọ atunto, kijọba si ṣepade pẹlu awọn janduku, Boko Haram- Awọn agbaagba ilẹ Hausa

Ẹgbẹ awọn agbaagba ilẹ Hausa ti wọn n pe ni Northern Elders Forum atawọn ẹgbẹ bii mẹtadinlogun mi-in lati Oke-Ọya ti sọ pe awọn gba pe ki atunto ba eto iṣejọba nilẹ wa, wọn ni ṣiṣe atunto si ofin ilẹ wa yii ni yoo jẹ ki ilẹ wa le ṣe amulo awọn anfaani to ni nipa ọrọ aje ati eto oṣelu.

Wọn sọ eleyii di mimọ lẹyin ipade ọlọjọ meji kan ti wọn ṣe ni Arewa House, niluu Kaduna, nibi ti wọn ti fẹnu ko lori koko mejila ti wọn sọ pe awọn fẹẹ mojuto gẹgẹ bii ẹya ilẹ Hausa.

Lara koko mejila naa ni wọn ti sọ pe ki a ṣe atunto ofin ati iṣejọba ilẹ yii lawọn fara mọ, wọn ni eyi ṣe pataki lasiko yii nitori igbesẹ yii ni yoo so wa pọ gẹgẹ bii orileede kan.

Bakan naa ni wọn sọ pe ko si ibanilorukọ jẹ tabi ohunkohun ti ẹnikẹni le sọ tabi ṣe, tabi ki ọwọ awọn bọ, ti awọn eeyan apa Oke-Ọya yoo fi ṣe ipinnu pe ki wọn maa pin ipo aarẹ kaakiri awọn agbegbe ilẹ wa.

Bakan naa ni wọn tun pe akiyesi awọn eeyan si ipo ẹlẹgẹ ti orileede Naijiria wa bayii, wọn ni bi Naijiria yoo ba yi ipo to wa yii jẹ, afi ki gbogbo ẹya ni orileede yii fọwọsowọpọ fun wiwa ni ọkan Naijiria.

Awọn eeyan naa ni awọn ti ṣetan lati jokoo ipade pẹlu awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti wọn ba ti ṣetan lati jokoo ipade pẹlu awọn lori ọjọ iwaju Naijiria. Wọn fi kun un pe gbogbo ẹdun ọkan ẹnikọọkan ni amojuto le wa fun ti a ba wa ni ọkan.

Bakan naa ni wọn koro oju si bi wọn ṣe ni awọn kan n pa awọn eeyan agbegbe naa ni apa isalẹ Odo-Ọya. Ẹgbẹ yii ni ijọba apapaọ ati ti ipinlẹ gbọdọ gbe igbesẹ to nipọn lati daabo bo awọn eeyan agbegbe naa to n gbe ni apa isalẹ.

Wọn ni ki i ṣe ki wọn ṣe amojuto yii nikan bi ko ṣe ki wọn mu wọn, ki wọn si fiya to tọ jẹ awọn eeyan ti ọwọ ba tẹ pe wọn n hu iru iwa bẹẹ.

Lara ohun ti wọn tun fẹnu ko si ni pe ki ijọba apapọ ṣe atilẹyin si ṣiṣe ipade pọ pẹlu awọn jandukun agbebọn, awọn Boko Haram ati awọn agbegbe ti wọn ti n ṣọṣẹ, ki alaafia le jọba ni Oke-Ọya.   

Yatọ si eyi, wọn rọ awọn gomina to wa lati apa agbegbe naa lati ri i pe wọn ko faaye gba ifosi-wẹwẹ agbegbe ọhun. Wọn ni ohun ti yoo dara ni bi aọn ba le wa ni ẹyọ kan gẹgẹ bii ẹya ju ki wọn maa sọ pe awọn ẹya kan lo kere ju, awọn kan lo tobi. Bẹẹ ni wọn fẹnu ko lati yanju awọn wahala abẹle lọlọkan-o-jọkan to n ṣẹlẹ kaakiri agbegbe naa.

Leave a Reply