Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq tipinlẹ Kwara ṣe ifilọlẹ igbimọ ẹlẹni mẹfa kan lati ṣewadii bijọba to lọ labẹ idari Dokita Bukọla Saraki ati gomina ana, Abdulfatah Ahmed, ṣe ta dukia ijọba laarin ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 1999 si ọdun 2019.
Adajọ-fẹyinti Ọlabanji Oriloniṣhe ni wọn fi ṣe alaga igbimọ naa. Awọn to maa ba a ṣiṣẹ ni; Ọgbẹni Job Kọlawọle Buremọh; Isiaka AbdulKarem (mni); Safiya Usman; Alhaji Salihu Yaru; ati Muhammed Baba Orire (Akọwe).
Atẹjade kan lati ọwọ Akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, ni igbimọ ọhun ni oṣu meji lati pari iwadii wọn, ki wọn si jabọ fun ijọba.
Wọn yoo ṣewadii lori bijọba ana ṣe ta awọn dukia naa ati ilana ti wọn lo lati ta wọn; boya o ba ofin mu tabi bẹẹ kọ.
Bakan naa, wọn yoo yẹ ẹ wo finnifinni boya o tọna bi wọn ṣe gbe awọn dukia naa ta, wọn yoo dabaa bijọba ṣe le ri awọn dukia ti wọn ta lọna ti ko bofin mu naa gba pada.
Bakan naa ẹwẹ, gomina tun gbe igbimọ oluwadii kan kalẹ lati ṣewadii bi wọn ṣe ni owo kan n poora lapo ijọba ibilẹ. Awọn to yan sinu igbimọ naa ni; Adajọ fẹyinti Mathew Adewara (Alaga); aṣoju ajọ ọtẹlẹmuyẹ, (DSS) Halimah Bello; aṣoju ọlọpaa, DSP Adekunle Iwalaiye; aṣoju ajọ ti ki i ṣe tijọba, (The Corinth’s Humanitarian Foundation) Titilayọ Adedeji; aṣoju ajọ ICAN, Mohammed Baba Ibrahim; aṣoju ẹka eto idajọ, NBA, Bello Aisha Mohammed; aṣoju ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC, Asmau Apalando; ati akọwe agba kan, Abilekọ Sabitiyu Grillo (Akọwe).
Ọsẹ meji pere lo ni igbimọ naa ni lati pari iṣẹ naa.