A gbọdọ bẹrẹ si i tumọ awọn ofin wa si ede abinibi bayii – Mudashiru Ọbasa

Faith Adebọla, Eko

Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, ti ṣalaye pe awọn ofin ilẹ wa ko le ye awọn eeyan yekeyeke, ayafi ti wọn ba bẹrẹ si i tumọ wọn si ede abinibi tawọn eeyan gbọ, ti wọn si mọ dunju daadaa.

Ọbasa sọrọ yii nigba to n gba awọn oṣiṣẹ ajọ to n ja fẹtọọ ọmọniyan lorileede yii (National Human Rights Commission, NHRC) lalejo lọfiisi rẹ to wa nile-igbimọ aṣofin Eko, Alausa, Ikẹja, lọjọ Abamẹta.

O ni lati kapa iwa ọdaran, awọn eeyan gbọdọ mọ ẹtọ wọn labẹ ofin, ṣugbọn ta a ba wo o, ede oyinbo lawọn aṣofin fi n ṣe ofin, ede oyinbo ni wọn fi kọ ọ, bẹẹ awọn ti ko fi bẹẹ kawe tabi ti wọn o tiẹ ka rara lo pọ ju awọn to mọwe lọ lawujọ wa. Sibẹ, ati ẹni to mọwe atẹni ti ko mọwe lofin wa fun, gbogbo wọn ni wọn wa labẹ ofin.

Ọbasa, to jẹ olori awọn aṣofin Eko rọ ajọ naa pe ki wọn sapa lati maa ṣe awọn eto ilanilọyẹ ati ipolongo wọn lede abinibi, ede ibilẹ tawọn eeyan gbọ lagbọọye ju ede oyinbo lọ, tori ofin ati ẹtọ tawọn eeyan ko ba mọ nipa ẹ maa ṣoro fun wọn lati pa mọ.

Bakan naa lo rọ ajọ ọhun lati fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn ajọ aladaani mi-in loju ọna ati wa ojuutu si iṣoro iwa ọdaran abẹle, ipinya ati ikọsilẹ to n ṣẹlẹ lemọlemọ laarin lọkọ-laya lasiko yii. Obasa ni ori bibẹ kọ loogun ori fifọ, ipinya ati ikọsilẹ kọ lo maa yanju ede-aiyede ninu idile, niṣe ni kawọn eeyan tubọ kọ bi wọn ṣe le gbe pọ lalaafia, ki tọtun-tosi si bọwọ fun ẹtọ ọmọlakeji ẹ.

Ṣaaju ni oluṣekokaari ajọ NHRC nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Lukas Koyejọ, to ṣaaju awọn alejo ọhun ti gboṣuba fun awọn aṣofin Eko, o ni awọn ofin to maa gbeja ẹtọ awọn olugbe ipinlẹ naa ni wọn n ṣe.

Leave a Reply