A gbọdọ tẹle ofin awọn eleto ilera ki korona ma baa tun wọ ilẹ wa lẹẹkeji-Buhari

Aderohunmu Kazeem

Lori ẹrọ agbọrọkaye rẹ, twitter, ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti rọ awọn ọmọ orileede yii pe ki wọn tele gbogbo ofin ati ilana ti awọn eleto ilera ti la kalẹ lori ọna ati dena arun korona nilẹ wa. O ni ọrọ aje ilẹ wa ko gbadun debii ka tun lugbadi korona lẹẹkeji.

Buhari ni titẹle awọn ilana yii ṣe pataki ki a ma baa tun lugbadi korona leekeji nilẹ wa. O ni ikilọ yii ṣe pataki ta a ba wo awọn ohun to n ṣẹlẹ lawọn orileede kaakiri agbaye bayii, nibi ti korona ti tun n ba wọn finra lẹlẹẹkeji.

Aarẹ ni a gbọdọ mura daadaa lati ri i pe bi ọrọ korona ti ṣe rọlẹ lọdọ wa, a ko tun ṣe ohun ti yoo mu ki o tun ṣẹ yọ mọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lẹyin ọdun mẹta ti tẹnanti tilẹkun ile pa, adajọ ni ki lanlọọdu lọọ ja a n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ilọrin paṣẹ ki …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: