A jọ n ta ko SARS ni, ṣugbọn mi o le maa sare kiri – Pasuma

Kazeem Aderohunmu
Ni nnkan bii ọjọ meloo kan sẹyin lawọn ọdọ kan bu ẹnu atẹ lu Alaaji Wasiu Alabi Pasuma, ẹsun ti wọn si fi kan an ni pe ọkunrin olorin fuji naa ko darapọ mọ awọn ọdọ Naijiria lati ṣewọde ta ko gbogbo ohun ti ijọba n ṣe tawọn ko fẹ.
Bi wọn ṣe sọrọ yii, bẹẹ niroyin ti gbe e, ṣugbọn ọkunrin onifuji yii naa ti sọrọ o, o ni awọn eeyan kan naa lo sọ pe gbogbo ẹni tọjọ ori ẹ ba ti ju aadọta ọdun lọ, kiru ẹni bẹẹ yee ṣe langbalangba bii ọdọ kiri.
Nibi ayẹyẹ kan to ti lọọ kọrin laipẹ yii lo ti kọ ọ lorin pe oṣu to n bọ yii, iyẹn oṣu kọkanla, ọdun yii, loun yoo pe ẹni ọdun mẹtalelaaadọta looke eepẹ.
Wasiu Alabi Pasuma sọ pe, “Gbogbo ohun ti awọn ọdọ ba ṣe pata lori ki Naijiria le dara, gbagbaagba ni mo wa lẹyin wọn, ko ṣẹṣẹ digba ti mo ba n sare tẹle wọn kiri. Gbogbo ori ẹrọ ayelujara mi, ‘officialpasuma’, la ti n ṣatilẹyin fun wọn.”
O fi kun ọrọ ẹ pe bi oun ko tiẹ jade, awọn ọmọ toun bi tawọn naa ti toju u bọ ti to lati kopa nibi iwọde ọhun nitori ọdọ Naijiria lawọn naa i ṣe.
“Laipe yii ni Wasilat, akọbi ọmọ mi yoo pe ọgbọn ọdun, bakan naa ni Barakat yoo pe ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, bẹẹ ni mo tun lọmọ mi-in to ti ẹni ọdun mẹrinlelogun. Fun idi eyi, lara awọn ọdọ Naijiria lawọn ọmọ mi yii wa, ti emi baba wọn ba si wa nile ti mo n fọkan ba wọn lọ, pẹlu awọn eyi ti mo ba le maa ṣe lori oriṣiiriṣii ikanni ayelujara ti mo ni, dajudaju a jọ n ṣe e ni.”
Tẹ ọ ba gbagbe, bí iwọde ọhun ṣe n lọ kaakiri orilẹ-ede yii lawọn olorin atawọn oṣere tiata kaakiri Naijiria naa jade lati ta ko iwa buruku ti awọn SARS n hu, atawọn ohun mi-in tawọn ọmọ Naijiria sọ pe ijọba gbọdọ wa ojútùú si.
Lara awọn oṣere to ti kopa daadaa tawọn eeyan n ri kiri ni Ṣeun Kuti, Eedris Abdulkareem, Saidi Osupa, Ọdunlade Adekọla, Davido, Small Doctor, Yọmi Fabiyi, Kikẹlọmọ Adéyẹmí, Rugged man ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply