A ko fọwọ si awọn to n lọ kaakiri ileewe pe ki ominira wa fun ilẹ Yoruba- Ijọba Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe oun ko mọ nnkan kan, bẹẹ ni oun ko ni ohunkohun i ṣe pẹlu awọn eeyan kan ti wọn n lọ kaakiri awọn ileewe nipinlẹ Ọṣun pe ki ominira wa fun ilẹ Yoruba.

Bakan naa nileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ l’Ọṣun kede pe ki awọn ọga agba ileewe mẹta tawọn eeyan ti wọn n polongo orileede Oodua ti de lọọ rọọkun nile fungba diẹ.

Ọnarebu Fọlọrunshọ Bamiṣayemi to jẹ kọmiṣanna feto-ẹkọ sọ pe ijọba ko fun ẹgbẹ kankan laaye lati maa lọ kaakiri awọn ileewe lati kede ọrọ ominira ilẹ Yoruba.

O ni gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla ko le fojuure wo ẹnikẹni to ba n gbe igbesẹ lati da iyapa silẹ lorileede Naijiria, bẹẹ ni ko ni i faaye gba ẹgbẹ to ba n wa iyapa lorileede yii.

Bamiṣayemi fi kun ọrọ rẹ pe ijọba nigbagbọ kikun ninu ala ati iran orileede Naijiria rere. O rọ gbogbo eeyan lati maa gbadura, ki wọn si maa ṣiṣẹ tọ bi orileede yii ko ṣe ni i tuka.

Ni ti awọn ọga agba ileewe mẹtẹẹta ti wọn ti faaye gba awọn ẹgbẹ to n polongo idasilẹ orileede Oodua kaakiri naa, Bamiṣayemi sọ pe wọn yoo foju winna abayọrisi iwa ti wọn hu.

Bakan naa ni Oludamọran pataki fun gomina lori eto ẹkọ, Ọnarebu Jamiu Ọlawumi, sọ pe o ṣe ni laaanu pe awọn eeyan kan le maa lọ kaakiri lati ko ọrọ buruku si ọpọlọ awọn ọmọ keekeke. O waa kilọ fawọn ẹgbẹ naa lati takete sipinlẹ Ọṣun nitori aṣoju rere fun iṣọkan orileede Naijiria lawọn akẹkọọ awọn yoo maa jẹ.

Leave a Reply