A ko gbọdọ da iṣẹ idagbasoke ilu da ijọba nikan – Salakọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Aarẹ ẹgbẹ idagbasoke ilu Ilobu, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Ọṣun, Pasitọ Olufẹmi Salakọ, ti sọ pe agbajọwọ ni iṣẹ idagbasoke ilu, ki i ṣe eyi to ṣee da ijọba nikan da.

Salakọ ṣalaye ọrọ yii nibi aṣekagba ayẹyẹ aadọta ọdun ti Olobu ti ilu Ilobu, Ọba Ashiru Ọlatoye Ọlaniyan (JP), gun ori-itẹ awọn baba nla rẹ.

O ni ẹlẹru lo gbọdọ kọkọ gbe e nibi to wuwo, ko too di pe ijọba ibilẹ tabi ti ipinlẹ yoo da si i, ki gbogbo nnkan le bọ soju ẹ ninu ilu.

Salakọ gboṣuba fun Ọba Ọlaniyan fun oniruuru idagbasoke to ti wọnu ilu naa lati ọdun 1974 to ti de ipo nla naa, o ni lai si ọwọ ijọba nibẹ, ọpọlọpọ nnkan ni kabiesi naa ru awọn ọmọ bibi ilu Ilobu soke lati ṣe.

O ni ileewe ijọba meji pere lo wa ninu ilu naa lasiko ti Ọba Ọlaniyan jọba, ṣugbọn aimọye ileewe ijọba ati ti aladaani lo ti wa nibẹ bayii, bẹẹ si ni ile-ẹkọ giga aladaani ti wa nibẹ pẹlu.

Ninu ọrọ tirẹ, Alaga igbimọ ayẹyẹ naa, Alhaji Abdulwahab Falọwọ, ṣapejuwe Ọba Ọlatoye gẹgẹ bii ọba to fi gbogbo ara jin fun igbega ilu naa, eyi to si n mu ki awọn ọmọ ilu maa ṣe rere kaakiri orileede yii, ati lagbaye.

O ni ilu naa ti ni igbakeji olori  ileegbimọ aṣofin apapọ lorileede yii, bẹẹ ni ọga agba ileeṣẹ ologun ilẹ lorileede yii lọwọlọwọ jẹ ọmọ bibi ilu Ẹdẹ.

Falọwọ sọ siwaju pe Olobuu fẹran alaafia pupọ, o si korira ohunkohun to le da omi alaafia ilu naa ru, idi si niyi ti awọn ọmọ bibi ilu naa nileloko fi sọ pe ayẹyẹ naa gbọdọ jẹ manigbagbe.

Lara awọn ti wọn yoo fi oye da lọla nibi ayẹyẹ ọhun ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, Yeyeluwa Modupẹ Adeleke-Sanni, Sẹnetọ Olubiyi Ajagunnla, Oniṣowo Azeez Ọlalekan Kọlade, Alaga fun agbarijọpọ awọn alaga ijọba ibilẹ l’Ọṣun, Ọnarebu Sarafadeen ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa ni awọn ori-ade kaakiri ipinlẹ Ọṣun, labẹ idari Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ẹni ti Aṣoya ti ilu Iṣọya, ṣoju fun, wa nibi ayẹyẹ aṣekagba naa.

Leave a Reply