A ko le awọn Ibo tabi ẹya kankan nilẹ Yoruba o – Olori Afẹnifẹre

Aderounmu Kazeem

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ti sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa fidio kan ti awọn eeyan n pin kiri bayii, ninu eyi ti wọn ti sọ pe ki awọn ẹya Ibo, fi gbogbo ilẹ Yoruba silẹ laarin wakati mejidinlaadọta.

Olori ẹgbẹ ọhun, Alagba Reuben Fasoranti, sọrọ yii niluu Akurẹ, nibi to ti sọ pe ẹgbẹ ọmọbibi awọn Yoruba yii ko mọ ohunkohun nipa fidio naa. Bẹẹ lo ni ki awọn eeyan ma ṣe ka iroyin ti wọn n pin kiri ori ikanni wasaapu (Whatsapp) atawọn ikanni ayelujara mi-in loriṣiiriṣi lori ọro yii kun rara.

Faṣọranti ni, “Ẹgbẹ wa kọ lo fi ọrọ ọhun sita, bo tilẹ jẹ pe awọn to ṣe e, orin wa ni wọn fi bẹrẹ ikede wọn. Mo fẹẹ fi da gbogbo aye loju wi pe awa ko mọ ẹnikẹni to n jẹ Adeyinka Grandson ri rara. Ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, bẹẹ la o ran an niṣẹ ko ba wa fun awọn ẹya Ibo tabi ẹya kankan ni gbedeke igba ti wọn gbọdọ fi ilẹ Yoruba silẹ.”

Baba yii fi kun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ Afẹnifẹre ko le ẹya kankan nilẹ Yoruba, bẹẹ lo rọ gbogbo araalu lati wa ni alaafia, to si fọkan awọn Ibo gbogbo to wa nilẹ Yoruab balẹ pe kinni kan ko ni i ṣe wọn.

 

Leave a Reply