A ko ni i gba ki ogun bori iran Yoruba ninu ile wa, a ṣetan lati daabo bo ara wa-Ọọni Ogunwusi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Arole Oduduwa, Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti sọ pe ṣe ni awọn agbebọn ti wọn ṣọṣẹ nileejọsin St Francis Catholic Church, Owa-luwa, Ọwọ, nipinlẹ Ondo, lọjọ Aiku, Sannde, to kọja, ninu eyi ti ọpọlọpọ eeyan ti gbẹmi-in mi, ti awọn mi-in si fara pa, fẹẹ sọ ilẹ Yoruba di ibudo ogun.
Ọba Ogunwusi ṣalaye pe awọn ọmọ Yoruba lagbara lati daabo bo ara wọn bo tilẹ jẹ pe wọn nifẹẹ alaafia pupọ.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin kabiesi, Ọtunba Moses Ọlafare, fi sita, Ọọni kilọ fun awọn afẹjẹwẹ ti wọn pinnu lati da wahala silẹ nilẹ Yoruba, to si jẹ pe awọn alaiṣẹ ni wọn maa n fori lu laluri iṣẹlẹ bẹẹ lọpọ igba.
“A gbọdọ ran ara wa leti pe ana, ọjọ Aiku, iyẹn ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, lo pe ọdun kan geerege ti awọn Fulani darandaran pa eeyan to le ni ogun niluu Igangan, nijọba ibilẹ Ibarapa, nipinlẹ Ọṣun, ti wọn dana sunle, ti wọn si dana sun aafin Aṣigangan lasiko ti gbogbo awọn eeyan n sun lọwọ.”
Ọọni ṣalaye pe iroyin ti n lọ kaakiri pe awọn ọdaran yii n gbero lati ṣakọlu si ilẹ Yoruba bii iru eyi ti wọn ṣe niluu Ọwọ lanaa.

“Bi iru eleyii ba ṣẹlẹ lai ni ibi kan ti eeyan le foju si, o tumọ si pe iṣẹ awọn oṣiṣẹ alaabo orileede wa ku diẹ kaato, tabi ko yọ rara. Amọ ṣa, a ko ni i gba ki ogun bori awa iran Yoruba ninu ile wa, a ti ṣetan lati daabo bo ara wa.
“Dipo ki wọn da omi tutu si wa lọkan, ṣe ni iṣẹlẹ yii yoo tubọ mu wa lokun si i, paapaa, ninu ipinnu wa lati lo agbara atinuda ati imọ-ẹrọ lori eto aabo ati dukia wa.
“Ki awọn gomina mẹfẹẹfa ti a ni nilẹ Yoruba atawọn ojugba wọn kaakiri orileede yii, to fi mọ Aarẹ Buhari, dide lati ṣe imuṣẹ ileri ti wọn ṣe nipa aabo awọn araalu”.
Ọọni ba Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, Ọba Ajibade Gbadegẹṣin Ogunoye 111, awọn eeyan ilu Ọwọ, Gomina Oluwarotimi Akeredolu, awọn iranṣẹ Ọlọrun ninu ijọ St. Francis Catholic Church, Ọwa-luwa, Ọwọ, mọlẹbi awọn to jade laye, awọn ti wọn fara pa ati gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ondo, kẹdun lori ajalu naa.

Leave a Reply