A ko ni i tori atilẹyin ti Pantami ṣe fawọn afẹmiṣofo nigba kan yọ ọ nipo minisita-Ileeṣẹ Aarẹ

Pẹlu gbogbo ariwo ti araalu n pa pe ki wọn yọ Minisita fun eto ibanisọrọ ati lilo imọ ẹrọ fọrọ aje, Isa Pantami, nipo nitori awọn ọrọ to ti sọ lati gbe lẹyin awọn afẹmiṣofo bii Boko Haram, Taliban ati Al-Qaeda, to si sọ pe oun fara mọ awọn ohun ti awọn eeyan naa n ṣe, ileeṣẹ Aarẹ ti sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ, wọn ni gbọin gbọin lawọn wa lẹyin ọkunrin naa. O ni ki i ṣe ọrọ ti ọkunrin naa sọ ni awọn eeyan n tori rẹ ditẹ mọ ọn, bi ko ṣe nitori ipo to di mu.

Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Garba Sheu, lo sọrọ naa di mimọ ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. Ninu atẹjade kan to fi sita, eyi to pe akọle rẹ ni ‘Ipolongo lodi si Minisita fun eto ibanisọrọ ati lilo imọ ẹrọ fọrọ aje.’

Garba ni ileeṣẹ Aarẹ gba pẹlu ọkunrin naa pe bo tilẹ jẹ pe loootọ lo sọ awọn ọrọ naa, igba to ṣi wa ni kekere ti ko ti i gbọn lo sọ ọ. Ṣugbọn ni bayii, ohun gbogbo ti yipada.

O fi kun un pe minisita yii ko le sọ iru ọrọ bẹẹ jade mọ niwọn igba to ti bu ẹnu atẹ lu iru ọrọ bẹẹ, to si ti tọrọ aforiji.

Oludamọran Aarẹ ni minisita naa ti tọrọ aforiji fun awọn ọrọ to sọ lati fi kin ẹgbẹ afẹmiṣofo yii lẹyin ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin, ati pe ko le sọ iru rẹ mọ bayii. O fi kun un pe nigba to wa ni bii ogun ọdun soke lo sọrọ yii, ṣugbọn yoo pe ẹni aadọta ọdun lọdun to n bọ, ọjọ ti jinna si ọrọ to sọ naa.

O ni ti awọn ọmọ Naijiria ni ijọba Buhari n ṣe lati ri i pe ko sẹni to fi ẹtọ wọn du wọn,l wọn si jẹ aanfaani to yẹ lori eto ibanisọrọ igbalode.

 

Leave a Reply