A ko ni i yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu lai ṣepade pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ-Ijọba Apapọ

Lati ma mu inira ba awọn araalu ni ijọba apapọ fi ni aọn ko ti i ni yọwọ lori owo iranwọ epo bẹntiroolu, bo tilẹ jẹ pe ofin tuntun ti Buhari ṣẹṣẹ buwọ lu lori ọrọ epo bẹntiroolu (PIB) faaye gba eleyii. Wọn ni lati ma fi ara ni araalu lawọn ko fi ni i mu eleyii ṣe loju ẹsẹ.

Minisita kekere lori ọrọ epo bẹntiroolu nilẹ wa, Timpere Sylva lo sọrọ yii di mimọ. O ni ọgọjọ Naira ti wọn n ta epo bẹntiroolu naa ni wọn yoo ṣi maa ta a.

Minisita yii ni awọn mọ inira ti fifi owo kun owo epo lasiko yii yoo mu ba araalu, awọn si fẹẹ ṣepade pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ lati le ṣaṣaro lori bi ofin yii yoo ṣe ṣiṣẹ, ti awọn yoo si ti mojuto anwọn ọna to le gba fẹẹ mu inira ba araalu.  

 

Leave a Reply