A maa ṣamulo ọgbọn ibilẹ ati tigbalode fun iṣẹ Amọtẹkun – Kọmọlafẹ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Ọgagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, ti sọ pe ọgbọn ibilẹ ati tigbalode ni ikọ naa yoo maa lo nigba ti iṣẹ ba bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Kọmọlafẹ sọrọ naa niluu Ẹfọn Alaaye, lasiko to ṣebẹwo ilanilọyẹ sijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti, Ẹfọn Alaaye ati Ijero.

Ọgagun-fẹyinti naa ṣalaye pe ikọ Amọtẹkun yoo lo awọn nnkan ijinlẹ ati tibilẹ Yoruba lati daabo bo awọn eeyan lọwọ awọn adigunjale, ajinigbe atawọn ọdaran mi-in.

O sọ ọ di mimọ pe eto aabo to mẹhẹ ko ṣẹyin bi awọn eeyan ṣe kọyin si awọn nnkan abalaye tawọn baba nla wa fi n ṣe agbara, igbesẹ naa lo si le ran ilẹ Yoruba lọwọ lasiko yii.

Leave a Reply