A maa ṣewadii ipaniyan to ṣẹlẹ ni Lekki-Sanwo-Olu

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti pasẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Lẹkki lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nibi ti awọn ṣoja ti ṣina ibọn fun awọn ọdọ to n fẹhonu han lodi si SARS, ti awọn kan ku, ti ọpọ ninu wọn si wa ni ẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun. O ni ki awọn eeyan ṣe suuru.

Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ọgbọn inu nipinlẹ Eko, Gbenga Ọmọtọṣọ, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita lorukọ ijọba. O ni iwadii yoo bẹrẹ ni kia lori iṣẹlẹ naa.

‘‘Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe awọn kan yinbọn si awọn oluwọde lẹyin ta a pasẹ konilegbele nitori bi awọn ọmọ ita ṣe n fi iwọde yii boju, ti wọn fi n da wahala silẹ, ti wọn si n ṣe awọn araalu leṣe.

‘‘Ijọba ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, bẹẹ ni Gomina Sanwo-Olu ti paṣẹ fun awọn agbofinro ki wọn ma ṣe mu ẹnikẹni nitori konilegbele to ni ki awọn araalu ṣe nitori alaafia ti o jẹ gbogbo wa logun.

‘‘O rọ awọn araalu lati ṣe suuru, ki wọn ma si gba awọn ti wọn fẹẹ ja iwọde alaafia ti awọn ọdọ wa n ṣe yii laaye lati ja a gba, ki wọn si dori ipinlẹ yii kodo ṣe aṣeyọri lori eleyii.

O waa fi da gbogbo araalu loju pe gbogbo ohun to wa ni ikapa ijọba ni yoo ṣe lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn ara ipnlẹ Eko.

2 thoughts on “A maa ṣewadii ipaniyan to ṣẹlẹ ni Lekki-Sanwo-Olu

  1. BEENI, won nfi ipo won ni ara ilu Lara, kosi Igbadun kankan, Osun mefa niwon fi tiwa mo inu Ile fun Covid-19, laisi ounje tabi owo gba, mabinu. Awa odo (youth) tun nbere eto (right) wa, pipa niwon tun ni ki awon Soldier ma pawa, iru ijoba wo ni eleyi, Ijoba apaniyan.

Leave a Reply