A maa ṣakoso ijọba orileede yii ni, a ko ni i jẹ gaba lori araalu-Tinubu

Adewale Adeoye

Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bura fun lorileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe oun yoo ṣakooso ijọba orileede yii lọna ti yoo tu gbogbo araalu lara daadaa, o n i ki i ṣe pe oun yoo jẹ gaba lori wọn rara, o ni igba gbogbo loun yoo maa fi tẹti lati gbọ gbogbo ẹdun ọkan awọn araalu pata, ati pe oun yoo ṣakoso wọn ni, oun ko ni i jẹ gaba lori wọn.

Aarẹ Tinubu sọrọ yii di mimọ lọjọ Aje, Monde, ọjọ kọkandinlọgbọn, Oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lẹyin ti wọn ṣeto ibura fun un tan ni gbagede ‘Eagle Square,’ niluu Abuja.

Ninu ọrọ rẹ ni Aarẹ Tinubu ti sọ pe, ‘Mi  o ni i jẹ aarẹ apaṣẹ-waa rara lori awọn araalu mi, aarẹ ti yoo maa ṣoju yin, ti yoo maa ṣakoso orileede yii lọna ti ẹ n fẹ ni ma a jẹ fun gbogbo awọn ọmọ orileede yii pata.

‘Lati igba ta a ti n dibo nilẹ yii, mo fẹrẹ le sọ pe ibo to gbe mi wọle yii ko ṣẹlẹ ri, gbogbo awọn ta a jọ dupo naa pata ni wọn kunju oṣuwọn, Ọlọrun kan jẹ ki n bori ni, nidii eyi, mo ṣeleri fun yin pe ma a ṣakoso ijọba orileede yii daadaa, mi o ni i jẹ aarẹ apaṣẹ-waa ti ko ni i tẹti gbọrọ lẹnu awọn eeyan rẹ, a maa nawọ ifẹ si gbogbo awọn tinu n bi pata pe ki wọn gbagbe ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin, a ko ni i ta ẹnikẹni nu rara ninu ijọba wa. A fẹẹ ṣatunṣe sohun gbogbo to ti bajẹ tẹlẹ ni. Ifẹ tawọn baba nla wa fi lelẹ naa ni ma a tẹle.’

Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun bu ẹnu atẹ lu bi ijọba Buhari ṣe ṣọrọ owo Naira tuntun to waye lorileede yii. O ni ijọba oun yoo ṣagbeyẹwo nipa ọrọ owo Naira naa, tawọn yoo si gbe igbeṣẹ gidi nipa rẹ bi akoko ba to.

Aarẹ ni ‘ Mi o fara mọ gbogbo igbesẹ ijọba ana nipa ọrọ owo Naira ti wọn sare paarọ yẹn rara, igbesẹ naa ku diẹ kaato, paapaa ju lọ nigba ti wọn tun dọgbọn gba iwọnba owo to wa lọwọ awọn araalu, ti wọn si parọ fun wọn pe awọn fẹẹ ba wọn paarọ rẹ, ṣugbọn ti wọn ko fun wọn lowo ọhun pada mọ rara, okun ẹmi ọrọ aje orileede gbogbo ni owo jẹ, ko si yẹ kijọba kankan fọwọ yẹpẹrẹ mu un rara.

‘Owo ti wọn n gba lori owo tawọn eeyan n ya ni banki gbogbo paapaa ti pọ ju bayii, bẹẹ bi ele ori owo ọhun ba pọ ju, ko si bawọn oniṣowo yoo ṣe ri ere gidi nidii ọja tabi iṣẹ ti wọn ba lo iru owo bẹẹ fun. Nidii eyi, ijọba mi yoo ṣatunṣe sawọn nnkan wọnyi loju-ẹsẹ. Ki igbe aye idẹrun le de ba gbogbo awọn araalu yii pata’.

Siwaju si i, Aarẹ Tinubu ni lara ohun to ṣe pataki ju lọ foun lati ṣe ninu ijọba oun lakooko yii ni lati wa ojutuu si bọrọ aje ilẹ wa yoo ṣe goke agba daadaa, ti yoo si gberuu si i, ti yoo si jẹ kawọn ọdọ paapaa lanfaani lati ri iṣẹ gidi ṣe laarin ilu.

 

Leave a Reply