A maa ṣe iwọde tawọn ọlọpaa ko ba fun Baba Ijẹṣa ni beeli tabi ki wọn gbe e lọ sile-ẹjọ-Yọmi Fabiyi

Ọkan pataki ninu awọn oṣere ilẹ wa, Yọmi Fabiyi, ti sọ pe awọn maa ṣe iwọde ta ko bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe fi Baba Ijẹṣa sahaamọ lai fun un laaye beeli, ti wọn o si foju rẹ ba ile-ẹjọ latọjọ yii. O ni eyi ta ko ẹtọ ara ẹni ti afurasi ọdaran naa ni labẹ ofin, o ni niṣe ni wọn n fiya jẹ ẹ, ti wọn si n ṣe adabọwọ idajọ rẹ funra wọn, awọn o si le fara mọ eyi.

Ninu ọrọ kan to sọ lori ikanni Instagiraamu rẹ lori atẹ ayelujara, Yọmi kọ ọ sibẹ pe:

“Ti kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko ko ba ti lọọ fi pampẹ ofin gbe gbogbo awọn agbalagba tọrọ yii kan ba a ṣe ri i ninu fidio to n ja ranyin yii, ti wọn o si fun Baba Ijẹṣa ni beeli, a maa ṣe iwọde wọọrọwọ ni ile ijọba l’Alausa, ni olu ileeṣẹ ọlọpaa Eko, ati kaakiri awọn agbegbe Eko, a maa beere pe ki wọn gbaṣẹ lọwọ awọn adari ẹka ijọba to yẹ ki wọn dide si ọrọ yii ṣugbọn ti wọn dakẹ, tori eyi fihan pe wọn o mọṣẹ wọn niṣẹ niyẹn, wọn o kunju oṣuwọn, niṣe ni wọn n fowo ijọba ṣofo lasan.

“A maa ja fẹtọ ọmọbinrin tọrọ yii kan, ẹ jẹ ka ṣe eyi fun ọmọniyan. Ki i ṣe ọmọbinrin yii nikan la fẹẹ ja fun, a fẹẹ ja fun ẹtọ gbogbo awọn ọmọde ni.

“Tori bẹẹ, iba dara kawọn to yẹ ki wọn ṣiṣẹ lori ọrọ yii dide bayii.”

Yatọ si igbesẹ ti Yọmi Fabiyi loun fẹẹ gbe yii, awuyewuye nla ni iṣẹlẹ Baba Ijẹṣa yii ti da silẹ laarin awọn oṣere tiata si ara wọn, bẹẹ ni ariyanjiyan nla n lọ lori ọrọ ọhun lojoojumọ lori atẹ ayelujara. Bi awọn kan ṣe n sọ pe iwa ti oṣere naa hu buru jai, ki wọn maa fun un ni beeli, niṣe ni ki wọn jẹ ko gba ahamọ ọlọpaa sọda si kootu, ko si gba kootu tatare sọgba ẹwọn, bẹẹ lawọn mi-in n jiyan pe Baba Ijẹṣa jẹbi loootọ o, ṣugbọn ẹṣẹ rẹ ki i ṣe ti fifipa ba ọmọde lopọ, wọn ni o fọwọ kan ọmọ naa nibi ti o daa ni, awọn mi-in si n sọ pe niṣe ni lawọn kan dẹ pakute fun Baba Ijẹṣa lori ọrọ yii, wọn nika ni wọn ṣe fun un.

Nibi tọrọ de yii, ko ti i sẹni to mọ ibi ti igi ọrọ yii maa wo si, tori ojumọ kan, ọrọ tuntun lo n ru yọ lori iṣẹlẹ Baba Ijẹṣa.

Leave a Reply