Adewale Adeoye
Ni bayii, banki apapọ orileede Naijiria ‘Central Bank of Nigeria’ (CBN) ti lawọn maa fiya nla jẹ awọn banki ti wọn n tọju owo si ‘Deposit Money Bank’(DMB) ti wọn ba kọ owo Naira to ti gbo kujẹ-kujẹ lọwọ awọn araalu to jẹ onibaara wọn.
Atẹjade kan ti ọkan lara awọn ọga agba banki naa, Ọgbẹni Ṣolaja Ọlayẹmi, fọwọ si l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun 2024 yii, ti ẹda rẹ tẹ ALAROYE lọwọ ni wọn ti ṣe ikilọ pataki ọhun fawọn banki gbogbo lorileede yii pe wọn ko gbọdọ kọ owo Naira kankan lọwọ awọn araalu, paapaa ju lọ awọn owo to ti gbo kujẹ-kujẹ to wa nita bayii.
Atẹjade ọhun lọ bayii pe, ‘O ṣe pataki pupọ ka ran awọn banki ilẹ wa leti pe abala ẹsẹ ofin kan ti oṣu Keje, ọdun 2019, ṣi wa nita pe ko si banki kankan lorileede yii to gbọdọ kọ owo Naira ilẹ wa rara, bi a ba waa ri banki kan to faake kọri pe oun ko ni i gbowo to ti gbo kujẹ-kujẹ lọwọ awọn araalu tabi onibaara rẹ, iru banki bẹẹ maa jiya gidi labẹ ofin ilẹ wa, a ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa mọ bayii. Ko sowo Naira ilẹ wa kankan tawọn banki gbọdọ kọ lọwọ awọn araalu tabi onibaara wọn mọ, owo naa ibaa ti gbo kujẹ-kujẹ gidi, owo ilẹ wa ni, wọn si gbọdọ gba a lọwọ wọn ni.
Lara ojuṣe wọn ni pe ki wọn maa gbowo yoowu to ba ti jẹ tilẹ wa lọwọ awọn araalu ati onibaara wọn. Fun idi eyi, o ti deewọ fawọn banki gbogbo nilẹ wa lati kọ owo to ti gbo lọwọ araalu bayii.