A maa gbẹsan iku awọn Fulani darandaran ti wọn pa nilẹ Ibo- Ẹgbẹ Miyetti Allah

Ẹgbẹ kan to n ṣoju fawọn Fulani darandaran ni Naijiria, Miyetti Allah Kautal Hore, ti parọwa sijọba atawọn agbofinro lati fiya to gbopọn jẹ gbogbo awọn to ṣakọlu sawọn Fulani darandaran lapa Guusu/Ila-Oorun ilẹ wa, wọn ni iwa ifẹmiṣofo lawọn to ṣakọlu ọhun hu, awọn si maa gbẹsan lara wọn.

Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni agbenusọ fẹgbẹ naa, Ọgbẹni Saleh Alhassan, sọrọ yii lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan tileeṣẹ iweeroyin Punch ṣe fun un.

Alhassan ni oun gboṣuba fun bawọn ṣọja ṣe ṣakọlu sawọn kan ti wọn pera wọn ni IPOB (Indigenous People of Biafra), ti wọn si mu ọkan lara awọn aṣaaju wọn, Kọmanda Ikonso, ati awọn mẹfa mi-in balẹ.

O ni ko sorukọ mi-in toun maa pe awọn to n pa Fulani darandaran nilẹ Ibo ju afẹmiṣofo ẹda lọ, o lawọn naa ni wọn n lọọ dana sun awọn teṣan ọlọpaa, ọgba ẹwọn ati awọn ile ijọba kaakiri agbegbe ọhun.

“Ta a ba ka a leni, eji, o ti ju aadọta awọn Fulani darandaran ti wọn pa lapa Guusu/Ila-Oorun orileede yii laarin oṣu kan pere, a lakọsilẹ rẹ, a si n ṣiro gbogbo bi wọn ṣe n pa wọn, a si maa ri i daju pe awọn Ibo apanilaya ti Nnamdi Kanu n ko kiri wọnyi jiya iwa buruku wọn, gbogbo ẹni kọọkan Fulani darandaran ti wọn pa la maa gbẹsan ẹ lara wọn.

“Awọn eeyan yii ti gbagbe itan ni o, ko si daa bẹẹ. Wọn ti gbagbe ba a ṣe daabo bo ẹmi awọn Ibo nilẹ Hausa lasiko ogun abẹle, tawọn waa n pa awọn eeyan tiwa lasiko yii. Aṣiṣe nla gbaa ni wọn ṣe. Gbogbo igbesẹ to ba yẹ ka gbe la maa gbe lati gbẹsan pipa ti wọn pa awọn eeyan wa, iba jẹ igbesẹ ofin tabi ti aṣa.”

Bẹẹ lọkunrin naa sọ.

Leave a Reply