A maa yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu ti ibo ablẹle wọn ba mu wahala dani danu ni- INEC

Faith Adebọla

Ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent Electoral Commission (INEC), ti kede pe lati asiko yii lọ, ẹgbẹ oṣelu eyikeyii ti ko ba le ṣeto idibo abẹle rẹ nirọwọ-rọsẹ, to jẹ pẹlu ija ati jagidijagan ni wọn ṣe e, niṣe lawọn maa yọ orukọ iru ẹgbẹ bẹẹ danu.

Atẹjade kan lati ọfiisi Agbẹnusọ ajọ INEC, Ọgbẹni Festus Okoye, ti wọn fi lede lọjọ Aje, Mọnde yii, sọ pe ajọ INEC ko le fọwọ lẹran, ki wọn maa wo awọn ẹgbẹ oṣelu bi wọn ṣe n ṣeto idibo abẹle lati yan awọn oloye ẹgbẹ wọn pẹlu wahala, jagidijagan, itahun-sira-ẹni, fa-a-ka-ja-a ati lilo awọn janduku.

Okoye ni ọpọ idibo abẹle tawọn ẹgbẹ oṣelu kan lawọn n ṣe ni ki i lori, ti ki i nidii, wuruwuru ati jibiti ibo lo maa n waye nibẹ.

O ni nigba mi-in, awọn arijagba ti wọn lawọn n ṣeto idibo abẹle tun maa n kọ lu awọn oṣiṣẹ ajọ INEC tawọn ba ran lọna ofin lati lọọ wo bi eto idibo ọhun ba ṣe lọ si. Ọkunrin yii ni ọpọ igba lo jẹ pe ọsibitu niru awọn ọbusafa (observer) bẹẹ maa n balẹ si latari akọlu ti wọn ba ṣe si wọn.

O waa ni lati asiko yii lọ, yatọ si pe ẹgbẹ oṣelu to ba faaye gba wahala nibi eto idibo abẹle wọn debi ti wọn fi ba dukia INEC jẹ maa ra iru nnkan bẹẹ pada, awọn tun maa yọ orukọ ẹgbẹ naa danu ninu akọsilẹ awọn bii ẹni yọ jiga ni. Tawọn ba si ri i pe ọrọ naa le pupọ, o ṣee ṣe kawọn ba iru ẹgbẹ oṣelu bẹẹ ṣẹjọ pẹlu.

Agbẹnusọ yii ni ajọ INEC tun le pinnu lati ma ṣe fi oṣiṣẹ wọn kankan ṣọwọ sibi tiru eto idibo abẹle oniwahala bẹẹ ba ti fẹẹ waye, bẹẹ gẹgẹ bii ofin, eto idibo abẹle ti oṣiṣẹ ajọ INEC ko ba lọwọ si, ofuutufẹẹtẹ lasan niru eto ọhun, gẹgẹ bi ofin ti la a kalẹ.

Leave a Reply