Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Idile ọlọmọọba Arutu Oluokun, nibi ti Ọrangun tilu Ila, Ọba Wahab Oyedọtun, ti wa, ti leri pe ẹnikẹni to ba tun sọ isọkusọ nipa mọlẹbi naa nibikibi yoo foju bale-ẹjọ.
Ninu atẹjade kan ti olori ile naa, Ọmọọba Ọlayiwọla Abimbọla, fun ALAROYE lopin ọsẹ to kọja ni baba naa ti sọ pe oun to ṣẹlẹ lọdun to ti pẹ sẹyin lawọn kan ti wọn fẹẹ tun itan kọ fi n peri idile awọn bayii.
Ọmọọba Abimbọla ṣalaye pe Ọrangun kan wa to ti jẹ laimọye ọdun sẹyin, ṣugbọn to bo gbogbo awọn nnkan ẹṣọ-ọba mọlẹ sibi kan ti wọn n pe ni Ila Yara, latari pe ko ni arole nigba to fẹẹ ku.
Nigba ti Ọba Oyedọtun waa de ori oye lawọn kan ti wọn jọ du oye bẹrẹ si i sọ isọkusọ kaakiri pe idile ọba naa lo bo awọn nnkan ẹṣọ-ọba mọlẹ.
O ni awọn dakẹ latọjọ yii nitori pe awọn ro o pe awọn eeyan ọhun yoo jawọ ninu iwa ibanilorukọjẹ ti wọn n hu kaakiri, ṣugbọn ni bayii to da bii ẹni pe wọn pinnu lati ma ṣe jawọ, o di dandan kawọn jẹ ki araalu mọ ododo ọrọ.
Baba yii ni idile ọlọmọọba Arutu Oluokun ko ni nnkan kan an ṣe pẹlu iṣẹlẹ to ti ṣẹlẹ laarin 1314 AD si 1353 AD, ẹnikẹni ko si gbọdọ sọ awọn lorukọ ti ki i ṣe tawọn.
O ni Ọba Adedọtun ni Ọrangun kẹta ti yoo jẹ lati idile Arutu Oluokun, ko si si ọmọ ilu Ila ti ko mọ akoko ọba naa si rere nitori oriṣiiriṣii iṣẹ idagbasoke lo n wọnu ilu naa wa lati ọdun mẹtadinlogun sẹyin to ti gun ori-itẹ awọn baba-nla rẹ.