A n ba ijọba sọrọ lọwọ lori bi wọn ṣe fagi le isin aisun ọdun tuntun l’Ọṣun – CAN

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyinti Kristi (CAN), ẹka tipinlẹ Ọṣun, ti sọ pe awọn ti bẹrẹ ifikunlukun pẹlu ijọba lori ikede ti wọn ṣe pe ko gbọdọ si isin aisun ọdun tuntun (Cross over nights service).

 

Alaga ẹgbẹ naa, Bishop Amos Ogunrinde, ṣalaye pe loootọ nijọba n wa gbogbo ọna lati ri i pe arun Koronafairọọsi ko tan kaakiri lasiko ọdun yii, sibẹ, awọn nigbagbọ pe ijọba yoo tun ero rẹ pa lori ikede naa.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nijọba kede nipasẹ akọwe agba pe ko gbọdọ si ipejọ nibikibi fun isin aisun ọdun lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, mọjumọ ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021.

 

Ṣugbọn ẹgbẹ onigbagbọ sọ pe bii igba tijọba kan fẹẹ ka awọn onigbagbọ lapa ko nikede naa. Ogunrinde ṣalaye pe awọn adari ẹgbẹ onigbagbọ atijọba ti n ṣepade lori ọrọ naa, awọn si gbagbọ pe ijọba yoo ṣekede mi-in ko too di alẹ ọjọ aisun ọdun tuntun nitori gomina to maa n tẹti silẹ si igbe awọn araalu ni Oyetọla.

 

Ninu ọrọ tirẹ, alaga agbarijọ awọn Musulumi l’Ọṣun, Alhaji Mustafa Ọlawuyi, sọ pe igbesẹ ijọba lati dẹkun ikorajọpọ ọlọpọ ero ki i ṣe lati ni ẹnikẹni lara, bi ko ṣe fun alaafia gbogbo araalu.

Leave a Reply