Faith Adebọla
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, Economic and Financial Crimes Commission, (EFCC), ti ṣalaye idi tawọn fi ka Gomina ipinlẹ Anambra to ṣẹṣẹ kuro nipo, Williams Obiano, ẹni ọgọta ọdun, mọ papakọ ofurufu Muritala Mohammed, n’Ikẹja, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta yii, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e lọ sahaamọ wọn niluu Abuja. Wọn lawọn o fẹ ki ọkunrin naa sa lọ mọ awọn lọwọ ni, tori ẹsun ikowojẹ ni koto ọba ti wa lọrun ẹ tẹlẹ, niṣe lawọn n duro pe ko pari saa iṣakoso rẹ kawọn too mu un.
Alukoro apapọ fun ajọ EFCC, Ọgbẹni Wilson Uwajuren, sọ fawọn oniroyin lọjọ Tọsidee ọhun pe loootọ lawọn ti mu Ọgbẹni Obiano, ati pe akata awọn lo wa, o lawọn n ṣewadii bo ṣe na awọn owo kan lasiko iṣejọba rẹ.
“Ootọ ni, a ti mu gomina ana lọ sọdọ wa, nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ana la mu un. A ti gbe e lọ sọfiisi wa niluu Abuja, laaarọ ọjọ Furaidee.
“O pẹ ta a ti n sọ gomina yii, ọkan lara awọn afurasi wa ni. Ṣugbọn ofin ma-fọwọ-kan-ọmọ-mi tawọn gomina n janfaani rẹ lasiko ti wọn ba wa lori aleefa ni o jẹ ka ti mu un, eyi la fi duro titi to fi kuro nipo, ṣugbọn bi olobo ṣe ta wa pe o fẹẹ lọ siluu oyinbo, a ni lati lọọ duro de oun ati iyawo rẹ, Ebelechukwu, ni papakọ ofurufu, tori a o fẹ ko sa lọ mọ wa lọwọ,” Uwajuren lo ṣalaye bẹẹ.
Tẹ o ba gbagbe, bi Gomina ipinlẹ Anambra ṣe n kuro nibi ayẹyẹ to ti gbe ọpa aṣẹ fun gomina tuntun to jẹ lẹyin rẹ, Ọjọgbọn Chukwuma Chalse Soludo, bẹẹ loun atiyawo rẹ tẹkọ leti lọ si papakọ ofurufu Muritala Mohammed l’Ekoo, lati wọ baaluu kọja siluu Houston, Texas, lorileede Amẹrika, ṣugbọn awọn ẹṣọ EFCC ti n duro de e ni papakọ ofurufu naa, wọn si fi pampẹ ofin gbe oun ati iyawo rẹ.
Ohun ta a gbọ ni pe wọn fẹsun kan gomina ana naa pe ọna to gba na biliọnu mẹtadinlogun Naira ti wọn gba lọwọ ẹgbẹ to n ya ni lowo niluu oyinbo kan, Paris Club, wọn lo gbọdọ ṣalaye nipa ẹ, tori iwadii fihan pe niṣe ni wọn ṣowo naa mọkumọku.
Bakan naa ni wọn lọkunrin naa lẹjọ i jẹ lori owo tijọba n fun awọn gomina pe ki wọn fi ṣeto aabo nipinlẹ wọn, eyi ti wọn n pe ni Security Vote, wọn ni bo ṣe n nawo naa loṣooṣu ko ye ẹnikan.
Wọn tun lawọn iṣẹ ode kan wa ti gomina naa ṣe laṣepati, iye owo to si yẹ ki wọn fi ṣiṣẹ naa kọ ni wọn fi ṣe e, wọn niṣe lo kọ ebe owo gọbọi sori awọn iṣẹ ọhun. Lara iṣẹ naa ni papakọ ofurufu to loun fẹẹ kọ siluu Umueri, ti ko lori ti ko nidii titi to fi pari iṣakoso rẹ.
Ohun ta a tun gbọ ni pe wọn ti fi iyawo rẹ silẹ laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, bo tilẹ jẹ pe ọkọ rẹ ṣi wa lakata EFCC, tori iwadii lori awọn ẹsun naa ṣi n tẹsiwaju.