”A o ni i ṣatilẹyin fun aarẹ lati iha ilẹ Yoruba ati Ibo, ẹlẹyamẹya ni wọn”

Faith Adebọla

Aarẹ apapọ fun ẹgbẹ awọn Fulani darandaran onimaaluu lorileede yii, Alaaji Bello Bodejo, ti sọ pe awọn darandaran ko ni i ṣatilẹyin kankan fun ondije fupo aarẹ to ba yọju lati iha Guusu orileede yii lọdun 2023, o ni ẹri ti fihan pe awọn to n ṣejọba lati agbegbe Ariwa mọ eto iṣakoso daadaa ju wọn lọ.

Ninu ifọrọwerọ kan tọkunrin naa ṣe pẹlu iweeroyin The Sun, lopin ọsẹ to kọja yii, lo ti sọrọ naa.

Badejọ ni loootọ ni Naijiria jẹ ọkan naa, ṣugbọn iyatọ ti ko ṣeefoju fo da wa laarin awọn to n ṣejọba ati eeyan inu ẹ.

“Loootọ a gba pe ọkan naa ni Naijiria, sibẹ, a o ni i ṣatilẹyin fẹnikẹni to ba wa lati iha Guusu lati de ipo aarẹ. Aarẹ lati iha Ariwa lo san ju, tori awọn eeyan Oke-Ọya mọ eto ilu ati iṣejọba daadaa ju awọn eeyan Guusu lọ.

“Awọn eeyan Ariwa ti fi han pe ko si iyapa laarin wọn lagbegbe tiwọn. Wọn ki i sọ pe Fulani lẹnikan, Hausa lẹnikan, tibi tabi tọhun, ṣugbọn ko ri bẹẹ laarin awọn eeyan Guusu, ẹlẹyamẹya ni wọn. Iṣejọba awọn eeyan Oke-Ọya si daa ju ti Guusu lọ.

“Ti ọta rẹ ba ni ko o fọwọsọwọpọ pẹlu oun lati da ile baba ẹ ru, ṣe wa a fọwọsowọpọ pẹlu ẹ loootọ? Ko sẹni to jẹ ṣe bẹẹ. Ṣugbọn to ba lo ọgbọn alumọkọrọyi fun ẹ, to si da ile baba ẹ ru, iwọ lo maa geka abamọ jẹ lẹyin ẹ.

“Ko si bawọn eeyan Guusu ṣe le mọ ijọba i ṣe daadaa to tawọn eeyan ilẹ Hausa, tori awọn agbaagba ati olori ilẹ wa latijọ lo da awọn eeyan Ariwa lẹkọọ nipa eto iṣelu ati iṣejọba.”

Ọkunrin naa tun sọrọ lori ilana ifẹranjẹko ti ijọba Buhari n ṣeto rẹ. O ni ibaa jẹ eto RUGA tabi ti Cattle Colony, iyẹn ọgba ati agbegbe ifẹranjẹko ti wọn ya sọtọ, o lawọn ipinlẹ kọọkan gbọdọ ṣeto ibi kan fawọn Fulani darandaran ki alaafia le wa. O ni ọjọ ti pẹ ti eto bẹẹ ti wa, ki i ṣe ọrọ ode-oni, bẹẹ lo fẹsun kan awọn eeyan to n tako ilana naa, o ni ọgbọn lati ko owo ijọba jẹ ni  wọn n da.

“Gbogbo awọn gomina wọnyi, ki wọn too bi wọn ni eto ifẹranjẹko ti wa, awọn ijọba kan ṣakọsilẹ rẹ bii ofin nipinlẹ wọn, awọn mi-in ko si sọ ọ dofin, ṣugbọn o wa.

“Ohun to n ṣe wọn ti wọn o fẹẹ fun wa ni ilẹ ifẹranjẹko wa lasiko yii ni ko ye mi, ko ye mi rara ni.

Ọsẹ to lọ lọhun-un ni Gomina ipinlẹ Jigawa ranṣẹ pe mi ki n waa wo agbegbe ifẹranjẹko ti wọn ya sọtọ fawọn darandaran onimaaluu, ọsẹ meji ni mo lo nibẹ. Ṣugbọn niṣe ni Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, n fi ọrọ awa Fulani ṣe oṣelu, o fẹẹ sọ ara ẹ di olokiki lati ara wa.”

Bẹẹ ni ọkunrin naa wi.

Leave a Reply