‘A o ni i ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu to ba mu ondije funpo aarẹ lati Oke-Ọya’

Faith Adebọla

 Agbarijọpọ ẹgbẹ ajijangbara iha Guusu orileede wa ti fẹnu ko pe awọn o ni i ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu eyikeyii to ba mu ondije fun ipo aarẹ lọdun 2023 lati agbegbe Oke-Ọya, iyẹn ilẹ Hausa.

Ninu ipade pataki kan tawọn ẹgbẹ naa ṣe lọjọ kẹtala, oṣu ki-in-ni yii, l’Abuja, ni wọn ti ṣepinnu ọhun.

Awọn ẹgbẹ ti awọn olori ẹgbẹ wọn ṣoju fun nipade naa ni ẹgbẹ Afẹnifẹre lati Guusu/Iwọ-Oorun, iyẹn ilẹ Yoruba, Oloye Ayọ Adebanjọ lo ṣoju ẹgbẹ naa, ẹgbẹ Ohaneze Ndigbo lati apa Guusu/Ila-Oorun, eyi ti Ọjọgbọn George Obiozor ṣoju fun.

Bakan naa ni ẹgbẹ Middle Belt Forum lati iha Aarin-Gbungbun orileede yii, Ọmọwe Pogu Bitrus lo ṣoju fun wọn, nigba ti Oloye Edwin Clark ṣoju fun ẹgbẹ PANDEF (Pan Niger-Delta Forum) lati agbegbe Guusu ilẹ wa.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede lẹyin ipade wọn, eyi ti gbogbo wọn buwọ lu, wọn lawọn gba pe orileede yii ko ṣee pin si wẹwẹ, o gbọdọ wa lodidi, ṣugbọn atunto gbọdọ waye, ati pe ipo aarẹ gbọdọ lọ si agbegbe Guusu ti Aarẹ Muhammadu Buhari ba ti pari ọdun kẹjọ ijọba rẹ loṣu karun-un, ọdun 2023.

Atẹjade naa ka lapa kan pe:“Iwe ofin ilẹ wa ati eto Naijiria bo ṣe wa lasiko yii ni abawọn, o wọ, ko si le mu itẹsiwaju gidi kan wa, tori naa, a n beere fun atunto to lọọrin si iwe ofin orileede yii, a fẹ iwe ofin tuntun to maa mu ki nnkan wa lọgbọọgba, ti ko ni i si ojusaaju, to si maa mu idajọ ododo ati ẹtọ wa, gẹgẹ bii orileede kan, eto kan.

“A ri i pe to ba fi maa di ọdun 2023, awọn eeyan agbegbe Ariwa orileede yii yoo ti gbadun ipo aarẹ fun ọdun mẹjọ, tori ẹni wọn lo wa nipo, tori naa, ipo aarẹ gbọdọ lọ sọdọ awọn eeyan Guusu lọtẹ yii.

“A ke si gbogbo ẹgbẹ oṣelu pata lorileede yii lati ṣeto ki ondije fun ipo aarẹ wọn ninu eto idibo to n bọ jẹ ẹni to wa lati iha Guusu orileede yii.

“A o ni i ṣatilẹyin kankan fun ẹgbẹ oṣelu eyikeyii ti ondije fun ipo aarẹ rẹ ki i baa ṣe ẹni to wa lati agbegbe Guusu.

“A fẹ kẹ ẹ mọ pe ipilẹ kan ṣoṣo to le mu ki iṣejọba dẹmokiresi fẹsẹ rinlẹ ni ki dọgba-n-dọgba wa, ka si pin ipo ati agbara ijọba bo ṣe yẹ, lai si ojooro.”

Bakan naa lawọn ẹgbẹ yii koro oju si eto aabo to mẹhẹ ati ifẹmiṣofo, ijinigbe to n waye lemọlemọ kaakiri orileede yii, paapaa lapa Ariwa/Iwọ-Oorun, wọn si tun ke si ijọba atawọn agbofinro lati tunra mu, ki wọn fi kun iṣapa wọn.

Wọn tun sin ileegbimọ aṣofin apapọ ilẹ wa ni gbẹrẹ ipakọ, wọn ni kidaa abadofin to maa mu ipindọgba, idajọ ododo, alaafia ati ajọṣe to dan mọran laarin awọn eeyan orileede yii waye ni ki wọn maa jirioro rẹ.

Leave a Reply