A o ni i gba ki wọn maa feeyan ṣetutu isinku ati ọba jijẹ- Olori awọn aṣofin Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

O ti ṣe diẹ ti aba kan ti wa nilẹ lori ọna ti wọn yoo maa gba sinku ọba nipinlẹ Ogun, pẹlu awọn aba mi-in to tun ni i ṣe pẹlu ọrọ ọba jijẹ. Lati ṣalaye ọrọ naa ko ye kaluku nitori awuyewuye to n da silẹ ni ile-gbimọ aṣofin ilu naa ṣe gbalejo awọn Oṣugbo l’Ọjọruu, ọjọ kẹrinla, oṣu keje yii, nibi ti  Ọlakunle Oluọmọ ti i ṣe abẹnugan ile naa ti ni ko ni i saaye fun fifi eeyan ṣetutu nigba ti wọn ba n fi ọba jẹ tabi sinku ọba alade.

Oluọmọ sọrọ yii lasiko ipade ita gbangba to waye nileegbimọ Ogun l’Oke-Mosan. O ṣalaye pe aba to wa nilẹ naa ki i ṣe fun isinku ọba ati jijẹ ọba nikan.

O ni o wa fun bawọn eeyan ilu mi-in ṣe maa n yan ajeji to lowo lọwọ ni oloye laarin ilu, dipo ki wọn ti baalẹ lẹyin, ki wọn mọ bi yoo ṣe jọba.

Ṣugbọn yatọ si eyi, ohun to mumu laya awọn Oniṣẹṣe ninu gbogbo aba naa ni eyi ti wọn ni ilana ẹsin ti ọba ba n sin ni ki wọn fi sin in.

Nigba to n ṣalaye nipa eyi, Oluọmọ sọ pe ko sẹni to ni ki wọn ma sin ọba nilana iṣẹṣe tabi ki wọn ma ṣe oro to yẹ. O ni ohun ti aba naa n sọ ko ju pe ko saaye fun fifi eeyan ṣetutu tabi oro nitori ọba to waja.

Abẹnugan ṣalaye pe aye ti laju ju aṣa bii eyi lọ, bi a ba si tiẹ tun yọ ti ọlaju kuro, o ni aṣa yii ta ko ẹtọ ọmọniyan lati gbele aye, nigba ti awọn kan ba n fi alaiṣẹ ṣetutu, nitori iku ẹni kan ṣoṣo. Eyi lo ni aba naa lodi si, ti aaye ko si ni i si fun un bo ṣe wu ko mọ.

Aṣoju awọn Oniṣẹṣe, Oloye Fagbemi Ifakorede, sọ ninu ọrọ tiẹ pe ika to ba tọ simu la fi n romu. O ni ko si ọna teeyan le fi ṣeto ọba lai lo ilana iṣẹṣẹ ta a daye ba tawọn baba nla wa si n lo.

Ifakorede sọ pe ilana isinku oniṣẹṣe ni wọn fi n sinku ọba, ati bi wọn ba ṣe n ṣe nibi ti ọba to waja ti wa. O ni ẹni to ba si ti fi ara ẹ silẹ lati jọba ti mọ ọna ti wọn yoo fi sinku rẹ, ko ruju rara.

Yatọ sawọn Oniṣẹṣe, awọn alẹnulọrọ mi-in naa wa nibi ipade yii, awọn bii aṣoju ‘Egba Traditional Council’, Ọba Olufẹmi Ogunlẹyẹ (Towulade Akinale) Imaamu Agba fun Gbagura; Ọjọgbọn Kamaldeen Balogun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gbogbo wọn ni ileegbimọ Ogun fun lanfaani lati da si ọrọ yii, awọn to ba si lohun ti wọn fẹẹ sọ si i ṣi le fi ero wọn ranṣẹ titi di ọjo Jimọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje yii.

Leave a Reply