A o ni i gba ọmọ ti ko ba pe ọdun mejidinlogun laaye lati ṣedanwo WAEC ati JAMB-Mamman

Adewale Adeoye

Ni bayii, ijọba apapọ ti sọ pe bẹre lati ọdun to n bọ, awọn ko ni i faaye gba ki akẹkọọ tọjọ ori rẹ ko to ọdun mejidinlogun maa ṣedanwo igbigbaniwọle sileewe giga lorile-ede yii, iyẹn ‘Joint Admission And Matriculation Board’ (JAMB).

Ṣa o, wọn ni ijọba apapọ maa faaye gba pe ki gbogbo awọn ti wọn ti gba foọmu ọhun lọdun yii tabi ti wọn ti kopa ninu idanwo ọhun lọdun yii lati wọle sileewe ti wọn fẹ.

Minisita fun ọrọ ẹkọ lorile-ede wa, Ọjọgbọn Tahir Mamman, lo sọrọ naa di mimọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, lasiko to n ba awọn oniroyin ileeṣẹ tẹlẹfiṣan Channel sọrọ l’ Abuja.

O ni, ‘‘Ki i ṣe pe ijọba apapọ ṣẹṣẹ ṣe ofin yii, ofin to ti wa nilẹ lati ọjọ pipẹ ni, awọn araalu lo kan n tẹ ofin naa loju mọlẹ bo ṣe wu wọn. Ṣugbọn ni bayii, a gbọdọ bọwọ fun ofin naa, a si gbọdọ ṣamulo rẹ ni. Ọmọ tabi akẹkọọ gbọdọ pe ọdun mejidinlogun ko too le ṣedanwo aṣekagba nileewe girama to n lọ, bẹẹ lọ gbọdọ pe ọmọ ọdun mejidinlogun ko too le ṣedanwo igbaniwọle sileewe giga fasiti. Awọn to ti ṣe tiwọn lọdun yii nikan la maa ṣaforiji fun, ṣugbọn bẹrẹ lati ọdun to n bọ, ijọba apapọ ko ni i faaye gba iru rẹ mọ lawujo wa. Ko si b’ọmọ naa ṣe le mọwe to, o gbọdọ pe ọdun mejidinlogun ko too ṣedanwo aṣekagba tabi eyi to maa fi wọle sileewe fasiti ni.

‘’Ba a ba ni ka foju ṣunukun wo o daadaa, b’ọmọ ba lo iye ọdun to yẹ nileewe rẹ, bẹrẹ lati kilaasi jẹle-o-sinmi, o maa pe ọdun mejidinlogun daadaa ko too pari ẹkọ rẹ nileewe. Bawọn alakooso eto ẹkọ ṣe n ṣe e lagbaaye niyẹn, ko yẹ ki tiwa yatọ rara. Ko si b’ọmọ ṣe le jafafa tabi mọwe to, o niye ọdun to gbọdọ lo ni kilaasi kọọkan ko too yege.

Leave a Reply