‘A tan Rofiat wa sile wa, lẹyin taa yin in lọrun tan la ge ori rẹ, oogun owo la fẹẹ fi i ṣe’

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Oru ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, laṣiri awọn ọmọdekunrin mẹta yii, mẹtadinlogun ( 17), Abdulgafar Lukman; ọmọ ọdun mọkandinlogun ( 19) ati Mustakeem Balogun, ẹni ogun ọdun(20), tu nibi ti wọn ti n jo ori ọmọbinrin kan, Rọfiat, ninu apẹ. Awọn ni wọn pa a l’Oke-Arẹgba, l’Abẹokuta, wọn lawọn fẹẹ fi ori Rọfiat ṣoogun owo ni.

Mẹrin lawọn ọmọkunrin to ṣiṣẹ naa, eyi to jẹ ọrẹkunrin Rọfia gan-an ti wọn pe orukọ ẹ ni Sọliu ti sa lọ.

Ṣugbọn awọn mẹta lọwọ ba. Ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Adewusi Ṣẹgun to jẹ olori awọn ọlọdẹ adugbo naa lo ta awọn to yẹ ko gbọ lolobo, pe oun ri awọn gende mẹrin kan ti wọn n jo nnkan kan to da bii ori eeyan, ninu apẹ, oju ọna ni wọn si ti n jo kinni ọhun.

Nigba tawọn ti yoo mu wọn yoo fi de, Sọliu ti wọn ni oun lo n fẹ ọmọbinrin naa ti sa lọ. Awọn tọwọ ba yii lo waa jẹwọ pe Idi-Apẹ ni Rọfiat n gbe, wọn ni ọdun to kọja loun ati Sọliu bẹrẹ si i fẹra wọn.

Ọkan ninu awọn gende naa tilẹ ṣalaye bi wọn ṣe tan Rọfiat wọnu ile ti wọn ti pa. O ni nigba tawọn fẹẹ pa a, Sọliu sun le e lori, lo ba yi ori ọmọbinrin naa sẹyin, o si ni koun ge e, boun ṣe ge ori naa niyẹn pẹlu ada.

Nipa ohun ti wọn fẹẹ fi ori naa ṣe, wọn ni oogun owo lawọn fẹẹ lo o fun.

Bi wọn si ti ge ori naa tan ti wọn n jo o ninu apẹ, wọn ti di gbunduku ara to ku sinu apo, ẹjẹ n rin bala ninu iyẹn ati nilẹẹlẹ yara ti wọn ti pa ọmọbinrin naa.

Aarọ ọjọ yii naa lawọn eeyan gbe oku Rọfiat to ṣẹku lọ si mọṣuari ọsibitu Jẹnẹra Ijaye, l’Abẹokuta. Bẹẹ ni iṣẹ n lọ lori bi wọn yoo ṣe ri Sọliu to sa lọ mu, awọn tọwọ ba si ti ba ara wọn nibi ti wọn maa n mu awọn apaayan lọ.

Ohun to n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi ni pe nigba ti ọjọ ori awọn ọmọkunrin yii ko ju bayii lọ, ti wọn ti mọ bi wọn ṣe n paayan nipakupa nitori owo bayii, a jẹ pe wahala gidi wa niyẹn.

Ikilọ ni awọn agbofinro ṣaa n ṣe fawọn ọmọbinrin ti wọn n yan ọrẹkunrin ojiji, awọn tọjọ ori wọn ko to nnkan ti wọn n ni ọrẹkunrin, ti wọn tun n wa wọn lọ. Ewu buruku pọ nibẹ ni wọn wi, bẹẹ ni wọn ni kawọn obi paapaa maa ṣọ awọn ọmọ yii lọwọ-lẹsẹ.

Ero buruku pọ ninu awọn ọdọ iwoyi nitori owo, o fẹrẹ ma si kinni kan ti wọn o le ṣe lati d’olowo ojiji dandan.

Leave a Reply