A ti ṣetan lati ṣeto owo ta a le fi ran awọn darandaran lọwọ – Tinubu

Aarẹ orilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti ṣeleri pe ẹni yoowu ninu awọn to ba n ba oun ṣiṣẹ ti ko ba ṣiṣẹ ẹ bo ṣe yẹ, niṣe loun maa yọ iru ẹni bẹẹ nipo.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Tinubu sọrọ naa di mimọ lasiko to ṣepade pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ Apa Ariwa kan, Arewa Consultative Forum (ACF), nile ijọba, niluu Abuja.

Nigba to n sọ erongba rẹ lati ri i daju pe oun gbiyanju gbogbo agbara oun fun orilẹ-ede Naijiria, Tinubu ke sawọn ijọba ipinlẹ lati mu awọn eeyan agbegbe igberiko ni pataki, ki wọn si mojuto ijọba ibilẹ wọn lati ri i daju pe wọn n ṣe ohun to tọ fawọn to n gbe ni ẹsẹ̀kùkú.

“Mo dupẹ lọwọ awọn to n ba mi ṣiṣẹ fun akitiyan wọn, amọ nigbakuugba ti mo ba ri i pe ẹnikẹni ninu wọn n ja ọmọ Naijiria kulẹ ninu ojuṣe wọn, ma a yọ ọ nipo ni.

“Ma a rọ yin lati ke sawọn gomina yin. Mo n sa gbogbo ipa mi lati ri i daju pe owo to n wọle si wọn lapo latoke gbe pẹẹli si i. Kawọn naa loju aanu, ki wọn si tete maa ṣe nnkan tawọn eeyan igberiko wọn ba n fẹ. Awọn eeyan n gbe nigberiko. Ibẹ ni wọn ti n ṣiṣẹ, ti wọn ti n da oko, ti wọn n gbe. Ti ijọba ibilẹ o ba kun oju osunwọn to lati ṣiṣẹ wọn, awa gẹgẹ bii aṣiwaju wọn o gbọdọ fọwọ lẹran.

” Nigba ta a n wa ibo, ọdọ awọn ara igberiko yii ni a kọri si, nigba tọwọ wa tẹ ẹ tan, a o waa sa wa si Abuja, ohun la maa wa gbaju mọ”.

Bakan naa ni Aarẹ koro oju si ọrọ awọn ọmọ ti wọn ko ri ileewe lọ lawọn apa ibi kan lorilẹ-ede yii. O ni ko ni i jẹ itẹwọgba ninu iṣejọba oun, nitori eto ẹkọ ṣe pataki ninu idagbasoke orilẹ-ede.

“Ọrọ awọn ọmọ ti wọn ko ri ileewe lọ o le jẹ itẹwọgba. Ẹkọ ni a le lo fi gbogun ti iṣẹ ati oṣi, ohun to si gbe pupọ wa debi niyẹn. A gbọdọ lo ẹkọ wa lati sin awọn eeyan, ati lati mu ayipada rere ba igbe aye wọn. A gbọdọ mu igbelarugẹ ba ohun to jẹ eegun ẹyin fun eto ọrọ aje orilẹ-ede yii, eyi ti i ṣe eto ẹkọ funra ẹ. A si maa fọwọsowọpọ pẹlu yin lori eleyii daadaa.

“A ṣi n kọ orilẹ-ede Naijiria bii ile lọwọ, inu mi si dun pe ẹyin naa ti n tẹnu mọ idi ta a gbọdọ fi mura si ọrọ idagbasoke. A o le fara mọ ọrọ ohun amayedẹrun to n bajẹ lọ, ati iṣẹ ati oṣi to gogò lapa Ariwa ilẹ yii. A gbọdọ fopin si ohun to ṣokunfa gbogbo eyi’’.

Bakan naa ni Tinubu tun mẹnuba ọrọ eto aabo ati nnkan ọsin. O gboṣuba nla fun Oludamọran rẹ lori eto aabo, Mallam Nuhu Ribadu, fun iṣẹ takuntakun to n ṣe nigba gbogbo.

“Gbogbo eeyan lo n fẹ aabo, a si gbọdọ tun ṣe ọpọlọpọ inawo lori ohun eelo imọ ẹrọ. A maa ṣe e, mo fi n da yin loju. Gbogbo ẹmi ati ọkan wa la maa fi sinu ki aabo fẹsẹ rinlẹ ni Naijiria, ati lori awọn eeyan ibẹ.

“Ẹ ba awọn gomina yin sọrọ lati pese ilẹ lọpọ fun wọn. Ẹ sọ fawọn ẹlẹran ọsin lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ. Ọwọ ijọba ipinlẹ ni ọrọ ilẹ wa. A ti ṣetan lati ṣeto owo ta a le fi ran awọn darandaran lọwọ. A le ṣe e, a o si ribi ṣe e. Tawọn eeyan ilẹ Brazil ati Dutch ba le ṣe e, awa naa le ṣe e niyẹn”.

Aarẹ tun lo anfaani ijokoo awọn eeyan naa lati pe fun iṣọkan iilẹ Naijiria, ati atilẹyin fun ijọba rẹ, o ni, “Niwọn igba ta a ba wa papọ, leyii ti a gbọdọ jọ wa papọ, agbara n bẹ ninu iṣọkan wa. Agbara wa n bẹ ninu ba a ṣe jọ wa. Mo dupẹ lọwọ awọn ti wọn n ba mi ṣiṣẹ pọ, amọ mi o nii ro o lẹẹmeji lati gba iṣẹ lọwọ ẹnikẹni ti ko ba sin awọn ọmọ Naijiria bo ṣe yẹ”.

Lojuna ati le mu gbogbo awọn aba to to kalẹ naa ṣẹ, Aarẹ paṣẹ pe ki wọn gbe igbimọ ti yoo maa ṣamojuto lori awọn ọrọ naa dide. Akọwe ijọba apapọ, Sẹnetọ George Akume, lo fi ṣe olori igbimọ naa.

Aṣaaju ẹgbẹ ACF, Amofin Bashir Dalhatu, to ko awọn eeyan ẹ sodi, ki Aarẹ Tinubu ku oriire ọdun kan rẹ nipo, bẹẹ lo ni gbogbo ẹgbẹ lo ba a dupẹ lori oriṣiiriṣii aṣeyọri to ti ṣe, ati gbogbo akitiyan rẹ lori ilẹ Naijiria.

O ni gbogbo ileri to ṣe fawọn eeyan apa Ariwa ilẹ yii lasiko ibo, eyi to ti n mu ṣẹ nipasẹ atilẹyin rẹ, ti mu ki ifẹ rẹ tubọ pọ lookan aya awọn eeyan naa si i.

Leave a Reply