A ti bẹrẹ iwadii lori awọn ti ọlọpaa fiya jẹ lasiko iwọde Lẹkki – Kọmiṣanna

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti kede pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori awọn fọran fidio to ṣafihan awọn oluwọde kan ti wọn lawọn ọlọpaa fiya jẹ, ti wọn ṣe baṣubaṣu, o lawọn maa ṣedajọ ododo lori iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko fi sọwọ s’ALAROYE laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, o ni Odumosu sọ pe o ya oun lẹnu lati ri iru iṣẹlẹ bẹẹ, ṣugbọn awọn ni lati wadii, lati fidi ẹ mulẹ boya awọn ọlọpaa lo wa nidii ifiyajẹni naa tabi bẹẹ kọ.

O ni ọkan lara fidio naa ṣafihan awọn gende ti wọn ti bọṣọ lọrun wọn, ti wọn ko wọn sinu bọọsi kan pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lọwọ, ti apa ifiyajẹni si han lara wọn.

Kọmiṣanna Odumosu ni ohun toun ri ninu fidio naa ya oun lẹnu, oun si ti paṣẹ fun Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko to wa ni ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ (CID) ni Yaba, DCP Fayọade Adegoke, pe ko tọpinpin fidio naa, ko si ṣawari awọn to ba lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, lati fi wọn jofin.

Odumosu ni bo tilẹ jẹ pe ojuṣe awọn ni lati gbe ofin ro, kawọn si ri i pe awọn eeyan pa gbogbo ofin mọ nipinlẹ Eko, sibẹ, awọn ni ilana to fidi mulẹ, to si wa lakọọlẹ to n dari gbogbo igbesẹ ati ihuwasi awọn ọlọpaa pẹlu araalu, ilana naa ko si faaye gba ifiyajẹni tipa-tikuuku ati fifi ọrọ dunkooko mọ ni.

O ni tawọn ba ti pari iwadii, tawọn si ti mọ awọn awọn ọlọpaa to lọwọ ninu iṣẹlẹ ọhun loootọ, oun fi da araalu loju pe ko sọlọpaa to huwa aibofinmu bẹẹ tawọn maa daṣọ bo lori, wọn ni lati gba sẹria to tọ si wọn ni.

Leave a Reply