Gbenga Amos, Ogun
Ọrọ airoorun-sun-wọra ati idunkooko mọ ni to n waye lagbegbe Ọja-Ọdan latari bawọn Fulani daran-daran ṣe kọwe sawọn eeyan agbegbe naa pe ki wọn maa mura ija silẹ de awọn, awọn n bọ waa gba ilẹ ati oko wọn lati maa fi da maaluu awọn, tori ibẹ ni wọn ti ṣigun le awọn kuro lọjọsi, awọn si ti ṣetan lati pada wa, ọrọ naa ti detiigbọ awọn agbofinro ipinlẹ Ogun, wọn si ti bẹrẹ iwadii ijinlẹ lati mọ awọn amookunṣika ti wọn kọ lẹta ijaya ọhun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ f’ALAROYE lori aago pe loootọ lawọn ti ri ẹda lẹta ati posita ti wọn kọ lori ọrọ to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara naa, ati pe kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ lati fimu finlẹ, ki wọn mọ orisun ti iwe apanilaya bẹẹ ti wa.
Aarin ọsẹ to kọja yii, iyẹn ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ọdun yii, lawọn olugbe agbegbe naa ṣadeede ri lẹta ati posita idunkooko mọ ni ọhun tawọn olubi ẹda kan ti pin kaakiri adugbo naa kilẹ too mọ. Ohun ti wọn kọ sinu lẹta naa ni:
“Kere o, kere o, kere o, ẹyin olugbe Asa, Agbọn, Ibeku, Ọja-Ọdan ati agbegbe rẹ la kọwe yii si o.
“Ṣe ẹ ro pe ẹ le le awọn eeyan wa kuro lori ilẹ ti wọn ra ni Naijiria, kẹ ẹ pa awọn eeyan wa, kẹ ẹ pa maaluu wọn, kẹ ẹ gba awọn dukia wọn, kẹ ẹ dẹ gba a gbe bẹẹ? O ti tasiko fun wa lati waa gbẹsan.
Ki gbogbo ẹyin olori lawọn ilu ati agbegbe ta a darukọ yii lọọ maa mura silẹ de ogun gidi laarin oṣu Disẹmba yii si Januari ni o. A n bọ waa gba ogun awọn baba wa pada lọwọ yin”.
Bẹẹ ni lẹta ọran ti wọn kọ lede oyinbo ati Hausa naa ṣe ka.
Oyeyẹmi sọ ninu ọrọ rẹ pe alainilaari ẹda kan ni wọn maa wa lẹyin lẹta buruku yii, ṣugbọn gẹgẹ bii ọlọpaa, ko si idunkooko mọ ni eyikeyii tawọn maa foju yẹpẹrẹ wo, tori igi teeyan ba foju di le pada waa gun ni loju.
“A o ni i foju yẹpẹrẹ ẹ, iṣẹ ti n lọ labẹnu lori ọrọ naa, afẹfẹ maa fẹ, a maa ri furọ adiẹ lori ẹ, a maa tọpinpin awọn kọlọransi ẹda ti wọn n dunkooko ọhun.”
Tẹ o ba gbagbe, ọpọ awọn olugbe agbegbe yii ni wọn ti filu silẹ, ti wọn ṣọda sorileede alaamulegbe wọn, iyẹn Bẹnẹ, atawọn ilu mi-in latari akọlu awọn Fulani daran-daran lọdun 2021, eyi to fẹmi ọpọ eeyan ati dukia ṣofo lasiko naa.
Ọrọ yii tubọ buru si i nigba tawọn ọdọ agbegbe naa fibinu dana sun agọ awọn Fulani ti wọn n gbe ibẹ, lẹyin ti ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho ṣabẹwo sagbegbe ọhun, bẹẹ lawọn afurasi Fulani daran-daran kan ṣakọlu lati gbẹsan.
A gbọ pe latigba ti lẹta yii ti jade lawọn agbofinro ti n lọ ti wọn bọ lagbegbe ọhun, bẹẹ lawọn araalu naa ko ni ifọkanbalẹ rara.