A ti ko awọn ọlọpaa lọ sibi tawọn ṣọja n sọ tẹlẹ-Ọdunlami

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti ni kawọn araalu lọọ fọkan balẹ lori awọn sọja ti wọn ko kuro lawọn oju ọna marosẹ latari ede aiyede ti wọn lo waye laarin ileeṣẹ ologun ati ijọba ipinlẹ Ondo.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Abilekọ Funmi Ọdunlami, lo sọrọ yii ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn oniroyin kan l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ wa yii.

O ni oun fi da awọn eeyan ipinlẹ Ondo loju pe ko ni i sewu fun wọn rara nitori pe gbogbo ọna marosẹ atawọn aala ipinlẹ Ondo tawọn ologun wa n ṣọ tẹlẹ lawọn ti ko awọn ọlọpaa si lati peṣe aabo fawọn araalu lasiko yii ti ọdun ti sun mọle.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa tete gbe igbesẹ naa kawọn ọdaran atawọn oniṣẹẹbi too bẹrẹ si i fi iṣẹlẹ ọhun kẹwọ lati ṣiṣẹ ibi wọn.

Ọdunlami gba awọn araalu atawọn onimọto nimọran lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya, bẹẹ lo rọ wọn ki wọn tete maa fi ohunkohun to ba n ṣẹlẹ layiika wọn to awọn ọlọpaa leti.

Leave a Reply