A ti mọ bareke tawọn ṣọja to paayan ni Lẹkki ti wa- Falana

Amofin agba, Fẹmi Falana, ti sọ pe aṣiri bareke tawọn ṣọja to kọ lu awọn eeyan ni Too-geeti Lẹkki, nipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti pa awọn to n ṣewọde ti tu si oun lọwọ bayii.

Ajọ kan ti orukọ ẹ n jẹ ASCAB, eyi to ni i ṣe pẹlu bi awọn eeyan ṣe le jajabọ lasiko ti wahala arun koronafairọọsi gbaye kan, ati lẹyin ẹ, lo sawari ibi tawọn ṣọja ọhun ti wa.

ALAROYE gbọ pe Fẹmi Falana yii gan-an ni alaga ajọ naa, o si ti sọ pe ninu iwadii ti ASCAB ṣe laṣiri ibi tawọn ṣọja ọhun ti wa ti tu sawọn lọwọ. Bakan naa lo fi kun un pe iwadii tawọn ṣe paapaa tun fidi ẹ mulẹ pe eeyan meji ni wọn pa lasiko ikọlu ọhun.

Lori eto kan to ṣe nileeṣẹ tẹlifiṣan kan lo ti sọrọ ọhun. O ni ohun to foju han bayii ni pe baraaki kan ni wọn ti wa, ohun to si daju ni pe Aarẹ orilẹ-ede yii mọ sọrọ ọhun, nitori ẹ gan an ni ko ṣe sọrọ lọ sibẹ nigba to ba gbogbo eeyan orilẹ-ede yii sọrọ laipẹ yii.

Bo tilẹ jẹ pe Amofin agba yii ko sọ ibi pato tawọn ologun yii ti ja bii iji wọ Lẹkki, ti wọn si rọjo ibọn lu awọn ọmọ ọlọmọ, sibẹ ko ṣai bu ẹnu atẹ lu bi ijọba ṣe n ko awọn ologun rọgba yi gbogbo ibi tawọn eeyan ti le kora jọ ṣewọde.

O ni, “Ohun itiju lo jẹ fun ijọba orilẹ-ede yii to sọ pe awọn eeyan lẹtọọ lati ṣewọde, ṣugbọn ti wọn n ko ṣọja jọ sawọn ibi ti wọn ti le fero wọn han lori ohun ti wọn ko fẹ. Dajudaju, ijọba yii ki i bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan rara”.

Lara awọn ibi ti Falana sọ pe wọn ko awọn ṣọja si bayii ni Gbagede Gani Fawẹhinmi, l’Ọjọta, niluu Eko, ati Unity Fountain, l’Abuja.

Leave a Reply