”A ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo lati doola akẹkọọ fasiti ti wọn ji gbe ni Kwara”

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn alaṣẹ ileewe giga Fasiti KWASU ti fi gbogbo awọn akẹkọọ to n gbe ninu ọgba ile-ẹkọ naa ati awọn to n gbe ni ita lọkan balẹ pe ki wọn mọ foya rara, ile-ẹkọ naa ti n ṣiṣẹ takun-takun pẹlu awọn ẹṣọ alaabo Vigilante ati ọlọpaa lati ri i pe wọn doola ẹmi Khọdijat kuro lakata awọn ajinigbe ti wọn ji i gbe.

Ninu atẹjade kan ti awọn alasẹ ile-ẹkọ ọhun fi sita ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, latọwọ adari ẹka iroyin ileewe naa, Abdulrazaq Sanni, ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe iroyin ibanujẹ kan de si etiigbọ awọn nipa Isiaq Khọdijat, akẹkọọ to wa ni ipele kẹta (300 level), ni ẹka Mass Communication, ti awọn ajinigbe ji gbe ni Opopona Okoru, niluu Malete.

Wọn ni awọn ti n sa gbogbo ipa awọn pẹlu ẹsọ alaabo lẹlẹka-jẹka lati ri i pe awọn doola akẹkọọ naa layọ ati alaafia. Wọn waa ni ki awọn akẹkọọ ma foya rara.

Giiwa agba ileewe ọhun, Ọjọgbọn MM Akanbi SAN, ti waa rọ gbogbo awọn akẹkọọ ati olukọ agbegbe naa lati maa rin tifuratifura, ti wọn ba si kẹẹfin ohun ajeji tabi iwa ko tọ kan, ki wọn fi to awọn alasẹ leti. Bakan naa lo rọ awọn akẹkọọ lati ṣọra fun irin alẹ, ki wọn si yee da rin. O rọ wọn ki wọn maa kọwọọrin nigbakuugba, tori pe airinpọ ejo lo n jẹ ọmọ ejo niya.

O waa fi da gbogbo awọn akẹkọọ loju pe awọn alaṣẹ ko ni i kuna lati maa pese aabo to peye fun ẹmi ati dukia gbogbo awọn akẹkọọ patapata.

 

Leave a Reply