A ti na to igba biliọnu Naira fun ipalẹmọ eto ikaniyan ti ko waye mọ yii-NPC

Adewale Adeoye

Ajọ eleto ikanniyan lorileede wa, ‘National Population Commision’ (NPA), ti sọ ọ di mimọ pe owo to to igba biliọnu Naira (N200) lawọn ti na bayii fun ipalẹmọ eto ikaniyan ti ajọ naa fẹẹ ṣe ninu oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii tẹlẹ, ko too di pe aarẹ orileede yii, Ajagun-fẹyinti  Muhammadu Buhari, paṣẹ pe ki wọn ṣi dawọ rẹ duro titi tijọba tuntun to n bọ lọna yoo fi wọle.

ALAROYE gbọ pe lara ẹgbẹrin biliọnu Naira (N800B), tawọn alaṣẹ ijọba ilẹ yii ya sọtọ ninu eto iṣuna owo tọdun yii fun ajọ naa ni wọn ti sare na igba biliọnu Naira (N200B), lori pe wọn n ṣegbaradi silẹ lasan.

Alaga patapata fun ajọ naa lorileede yii, Nasir Kwarra, lo sọrọ ọhun di mimọ niluu Abuja, lakooko to n ba awọn oniroyin kan sọrọ l’Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2203 yii.

O ni ki i ṣe ọwo kekere lawọn ti na lori awọn ohun eelo tawọn fẹẹ lo fun eto naa rara, paapaa ju lọ, ẹrọ kọmputa igbalode gbogbo tawọn fẹẹ lo atawọn nnkan miiran.

Bakan naa ni alaga naa tun sọ pe o le ni awọn oṣiṣẹ miliọnu kan tawọn ti gba sẹnu iṣẹ bayii, to si jẹ pe ojoojumọ lawọn n fun wọn ni idanilẹkọọ lati le ṣiṣẹ naa daadaa bi akoko ba to.

O ni, ‘O ṣe pataki fun wa lati wa ni igbaradi fun eto ikanniyan ọhun, oniruuru awọn ohun eelo la ti ra silẹ fun eto naa, a si tun ti gba ọpọ awọn oṣiṣẹ sẹnu iṣẹ, ojoojumọ la si fi n fun wọn ni idanilẹkọọ, ki wọn baa le ṣiṣẹ naa daadaa bi akoko ba to. Ki i ṣe owo kekere la ti na lori ipalẹmọ ati igbaradi silẹ fun eto naa bayii, ojoojumo aye la n fi n nawo, ki eto naa le kẹsẹjari layọ ati alaafia ni.

Ohun kan ṣoṣo ta a n beere lọwọ awọn oniroyin ilẹ yii ni pe ki wọn ma ṣe jẹ ko su wọn rara, gbogbo igba ni ki wọn maa ba wa tẹ ẹ mọ etiigbọ awọn alaṣẹ ijọba ilẹ yii, idi pataki ta a fi gbọdọ ṣeto naa ni kia bayii.

Siwaju si i, Ọgbẹni Inuwa Jalingo toun naa jẹ ọkan pataki lara awọn ọga agba nileeṣẹ ajọ naa tun kin alaga ajọ ọhun lẹyin pe wọn ko figba kankan sinmi rara lori bi eto ikanniyan ti ọdun yii yoo ṣe kẹsẹjari layọ ati alaafia bayii, o ni gbagbaagba bayii lawọn ti wa ni imurasilẹ fun eto naa nigbakuugba to ba to akoko lati ṣe e.

Leave a Reply