A ti ri oku akẹkọọ Fasiti Ifẹ to dawati lotẹẹli gbajumọ oniṣowo kan, iwadii si ti bẹrẹ lori ẹ-Ọlọpaa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe awọn ti ri oku akẹkọọ Fasiti Obafemi Awolowo, Timothy Adegoke, to di awati lọsẹ to kọja.

Atẹjade kan ti Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fi sita sọ ọ di mimọ pe awọn afurasi mẹfa ni ọwọ ti tẹ lori iṣẹlẹ naa.

O ṣalaye pe lati Abuja ni Timothy ti maa n wa fun ikẹkọọ ifimọkunmọ (Masters Degree) ni ẹka Fasiti OAU tibujoko rẹ wa niluu Moro, nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ.

Ọpalọla sọ siwaju pe laago mẹrin aabọ irọlẹ ọjọ keje, oṣu kọkanla, ọdun yii,ni awọn kan lọọ sọ ni tesan ọlọpaa to wa niluu Ẹdunabọn pe awọn ko gburo Timothy.

Lẹyin eyi ni wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran niluu Oṣogbo fun iwadii kikun lọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun yii.

Lọgan ni wọn bẹrẹ iwadii, lasiko yii ni wọn fi panpẹ ọba gbe eeyan mẹfa ti wọn n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadi lati mọ iru iku to pa ọmọkunrin naa.

Atẹjade naa fi kun un pe Kọmiṣanna ọlọpaa, Ọlawale Ọlọkọde, parọwa si awọn mọlẹbi ọkunrin naa ati awọn akẹkọọ Fasiti OAU lati ni suuru, nitori laipẹ ni wọn yoo tuṣu desalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply