Aadọta miliọnu lawọn to ji Dokita Fọlọrunshọ gbe ni Kwara n beere fun

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ajinigbe to ji Mọgaji Erubu, Dokita Zubair Fọlọrunshọ Erubu, gbe lọ niluu Agọ Ọja, Afọn, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, ti n beere fun aadọta miliọnu naira owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi.

Tẹ o ba gbagbe, alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lawọn agbebọn ti wọn o ti i mọ ji Mọgaji Erubu, Dokita Zubair Ọba Fọlọrunshọ, gbe lọ, tawọn mọlẹbi rẹ si sọ fun ALAROYE pe ọkunrin naa n bọ lati ibi iṣẹ oojọ rẹ ni awọn agbebọn to dihamọra pẹlu ohun ija oloro da a lọna niwaju ile ẹ, ti wọn si n yinbọn leralera lati fi dẹruba awọn olugbe agbegbe naa titi ti wọn fi gbe e lọ. Fọlọrunshọ ni wọn lo jẹ Mọgaji Erubu, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, to si tun jẹ dokita to ni ileewosan alaadani ni agbegbe Balogun Fulani, niluu Ilọrin.

Ni bayii, awọn ajinigbe ọhun ti pe mọlẹbi rẹ, ti wọn si n beere fun aadọta miliọnu naira owo itusilẹ lọwọ wọn ti wọn ba fẹẹ ri ọkunrin naa laaye.

Ọkan lara mọlẹbi to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe ohun to jẹ awọn logun ni ki wọn ri Dokita naa layọ ati alaafia, ki nnkan kan ma ṣe e.

Leave a Reply