“Aadọta miliọnu nijọba gbọdọ fun ẹbi kọọkan tawọn ọmọ wọn ku ni Lẹkki”

Aderohunmu Kazeem

Amofin kan, Yusuf Nurudeen, ti gbe ijọba lọ sile-ẹjọ lori awọn eeyan ti wọn pa lasiko iwọde ta ko SARS lagbegbe Lẹkki, l’Ekoo.

Ile-ẹjọ giga kan niluu Eko ni Nurudeen pe ẹjọ ọhun si. Lara awọn to si pe lẹjọ ni Aarẹ Muhammed Buhari, Gomina Babajide Sanwo-Olu, Ọga agba fun ileeṣẹ ologun, Ọgagun Tukur Buratai atawọn eeyan mẹsan an mi-in.

Ohun ti Amofin yii sọ ni pe yoo wu oun ki ile-ẹjọ paṣẹ fun ijọba lati san aadọta miliọnu fun ẹbi kọọkan ti wọn padanu eeyan wọn ni Too-geeti Lẹkki, l’Ekoo, nigba tawọn ṣọja yin wọn nibọn, nibi ti wọn ti n ṣe iwọde ta ko ẹṣọ agbofinro SARS.

Lara awọn ẹbẹ amofin yii nile-ẹjọ lo ti sọ pe ki adajọ paṣẹ pe bi awọn ṣọja ṣe yinbọn paayan ni Lẹkki ki i ṣe ohun to bojumu rara.

O ni oun ko ni igbagbọ ninu ohun ti ijọba sọ pe awọn ṣọja to lọọ koju awọn to n ṣewọde lọ sibẹ lati pa ofin konilegbele ti ijọba Eko paṣe ẹ mọ ni.  O ni, “Ohun ti mo mọ daju ni pe ki i ṣe ijiya iku lo wa fun ẹni to ba jẹbi ẹsun aitẹle ofin konilegbele, ati pe lasiko igba ti wọn bẹrẹ si i yinbọn paapaa, ofin konilegbele tijọba Eko paṣẹ ẹ, ko ti i bẹrẹ rara.

“Aago mẹsan-an nijọba Eko paṣẹ fun awọn eeyan ki wọn jokoo sile wọn, ṣugbọn igba ti awọn ṣọja bẹrẹ si i yinbọn yii, asiko ọhun ko ti i to rara.”

Amofin Nurudeen ti waa rọ ile-ẹjọ pe ko paṣẹ pe bi awọn ṣọja ṣe lọọ fi ipa tu awọn eeyan ka ni Too-geeti Lẹkki lọgunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii, ko tọna rara.

Bẹẹ lo sọ pe gbogbo awọn eeyan ti wọn pa nipakupa nibẹ ni ijọba gbọdọ ṣeto aadọta miliọnu fun ẹbi kọọkan ti wọn ṣofo eeyan wọn nibẹ.

Leave a Reply