Aago mọkanla alẹ ni ki gbogbo ṣọọṣi pari isin aisun ọdun tuntun l’Ekoo – CAN

Faith Adebọla, Eko

Ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Kristẹni, Christian Association of Nigeria, (CAN), ẹka ti Eko, ti paṣẹ fawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ pe ki wọn pari isin aisun ọjọ ọdun tuntun ni aago mọkanla alẹ ọjọ naa.

Ipinnu naa, to yatọ si aṣẹ tẹgbẹ ọhun ti kọkọ pa, lo wa ninu atẹjade kan ti Alaga CAN nipinlẹ Eko, Biṣọọbu Steven Adegbitẹ, fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, sọ pe ẹgbẹ naa ti ṣagbeyẹwo aṣẹ ijọba ati ọrọ Korona to n fojoojumọ gbilẹ bii ina ọyẹ lasiko yii.

Atẹjade ọhun lapa kan ka pe: Gẹgẹ bii ojuṣe wa lati fi han pe ẹgbẹ to n tẹle ofin ni wa, ati gẹgẹ bii ijọba ipinlẹ Eko ṣe parọwa si wa, a pa a laṣẹ bayii fun gbogbo awọn ṣọọṣi to jẹ ọmọ ẹgbẹ CAN nipinlẹ Eko pe ki wọn pari isin aisun ọjọ ọdun tuntun ni aago mọkanla alẹ, ki wọn si jẹ kawọn to waa jọsin tete pada sile wọn kaago mejila ti ofin konilegbele maa bẹrẹ to o lu.

Ẹgbẹ CAN ni awọn gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati mu adinku ba itankalẹ arun COVID-19, ki wọn ma si fi ọrọ aabo awọn ọmọ ijọ wọn ṣere.

Leave a Reply