Aara san pa maaluu meje niluu Alla

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Aara san pa maaluu meje, Fulani darandaran meji fara pa nigba ti ojo n rọ niluu Alla, nijọba ibilẹ Isin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe awọn Fulani darandaran ni wọn n da ẹran kiri lati ilu kan si ekeji, nigba ti wọn de ilu Alla, ti wọn si n lọ si Oke-Ọdẹ, ni ojo bẹrẹ si i rọ, ni wọn ba fara pamọ sinu oko kan to wa nitosi wọn, afi bi aara ṣe bẹrẹ si i san, nigba ti wọn yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ,  maaluu meje ti ku, awọn Fulani mejeeji si fara pa yannayanna.

Ẹlẹyin ju aanu kan lo ri wọn, to si lọọ sọ fun awọn araalu, eyi lo mu ki Ọba Alala ti ilu Alla, fi Ìṣẹ̀lẹ̀ naa to DPO ọlọpaa Oke-Onigbin ati awọn Fulani to wa ni agbegbe naa leti fun igbeṣẹ to yẹ.

Wọn gbe ọkan lara awọn Fulani to fara pa lọ si ileewosan Awoye, niluu Oro, o si n gba itọju lasiko ta a fi n kọ iroyin yii. Ọsunitu kan niluu Igbaja ni wọn gbe ẹni keji

Ninu ipade ti wọn ṣe laafin Ọba Alla pẹlu awọn Fulani, wọn fẹnuko pe ki ẹni to ni maaluu lọọ tọju awọn Fulani to fara pa, tori pe amuwa Ọlọrun ni.

 

Leave a Reply